Ọrọ yii ṣi maa dija: Wọn ti gba APC lọwọ Tinubu o

Nigba ti alaga igbimọ awọn gomina ẹgbẹ APC, Atiku Bagudu to tun jẹ gomina ipinlẹ Kebbi mu awọn gomina mẹrin mi-in dani lati lọọ ki Ọgagun Agba Muhmamadu Buahri ni Aso Rock pe o ṣeun ana, awọn ti ko mọ tẹlẹ ti waa mọ, awọn ti ko si gba naa ti gba pe, patapata nijọba bọ lọwọ Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga APC yii tẹlẹ, o si ti bọ sọwọ awọn mi-in ti wọn lagbara ju oun ati alatilẹyin rẹ lọ. Alatilẹyin Oshiomhole kan ko si ju Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọ, oun lo ni k’ọkunrin naa maa jo niṣo lati ọjọ yii wa, bo tilẹ jẹ pe ibi ti ijo naa waa yọri si yii ko daa. Awọn gomina to lọọ ki Buhari pe o ṣeun ọjọ ni Olori ẹgbẹ awọn gomina pata, Kayọde Fayemi ti Ekiti, Gomina ti Yobe ti wọn ṣẹṣẹ fi ṣe alaga igbimọ alaboojuto ẹgbẹ APC, Mai Mala Buni; Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello, ati Gomina ipinlẹ Kogi, Yahya Bello.

Ohun ti wọn tori ẹ lọọ ki Buhari ni oore ti wọn lo ṣe ẹgbẹ awọn, APC, pe oun gẹgẹ bii olori ẹgbẹ pata ni ko jẹ ki ẹgbẹ naa re sinu agbami, oun lo fa APC pada leti okun, to si jẹ ki awọn le bẹrẹ igbesẹ tuntun. Ọrọ naa jọ bẹẹ! Ṣe nigba ti yoo fi di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, ti wọn ṣepade yii, iye ẹjọ to ti wa ni kootu le ni meje, awọn ọmọ APC yii naa lo n pe ara wọn lẹjọ, afi bii igba tẹnikan da Ifa Ọwọnrin fun wọn, to si n kọrin Ifa tọ wọn lẹyin pe: ‘awọn ara wọn, wọn ko ṣai bara wọn ja, awọn ara wọn.’ Alaga pẹjọ, awọn ọmọlẹyin rẹ pẹjọ, adele alaga pẹjọ, akowe ẹgbẹ pẹjọ, ọmọ ẹgbẹ lasan pẹjọ, ọrọ naa si di iṣu-ata-yan-an-yan-an. Ohun ti Buhari ṣe ni kẹni to ni iwe idajọ to ga ju lọ lọwọ laarin wọn, Victom Gidiom, pepade awọn igbimọ apaṣẹ agba ẹgbẹ yii si inu Aso Rock ree, ki awọn le yanju ọrọ naa lẹẹkan.

Inu awọn igbimọ adari ẹgbẹ naa ti Oshiomhole jẹ alaga fun ko dun sipade yii, kia ni wọn si ti gbewee jade. Wọn ni bi ipade kankan ba fẹẹ waye, ki i ṣe Giadom ni yoo pe e, awọn lawọn gbọdọ pepade naa, ẹni ti yoo si pe e ni Hilliard Eta, ẹni ti i ṣe adele alaga, nitori oun lo n dele fun Abiọla Ajimọbi ti awọn adari ẹgbẹ yii ti yan laarin ara wọn pe yoo di ipo naa mu, lẹyin ti ile-ẹjọ ti yẹ aga mọ Oshiomhole nidii, ti wọn ni ko fipo alaga silẹ lẹsẹkẹsẹ. Kia ni wọn sare ṣepade laarin ara wọn, ti wọn si fi atẹjade sita pe awọn ko ni i yọju sipade naa, nitori ipade ti ko bofin mu ni, awọn ko si ni i gba ohun yoowu ti wọn ba sọ nibẹ wọle rara. Ẹnu ya awọn eeyan pe awọn kan yoo jokoo sibi kan, wọn yoo si maa ta ko Buhari ninu ẹgbẹ APC, wọn ni awọn yoo maa woran wọn. Ohun ti awọn ọmọ igbimọ adari yii fẹẹ ṣe ni lati lọ si ile ẹgbẹ APC lọjọ tawọn Buhari pepade, ki awọn naa ni awọn n ṣepade tawọn. Ṣugbọn ko ri bẹẹ fun wọn.

Ohun ti ko jẹ ki ọrọ naa ri bẹẹ ni pe nigba ti ilẹ yoo fi mọ lọjọ ipade yii, awọn ọlọpaa kogberegbe ti ya bo ile ẹgbẹ APC pata, wọn ti gbogbo geeti to wọbẹ pa: ko sẹni to le wọle. Akọwe igbimọ wọn, Alaaji Bulama, to kọkọ de lati ṣeto ipade tiwọn ko ribi wọle, awọn ọlọpaa le e sita. Ni gbogbo asiko ti wọn n le e, ipade ti Giadom pe si Aso Rock ti bẹrẹ, nibi ti Buhari funra rẹ wa pẹlu awọn gomina APC bii mẹẹẹdogun. Ipade naa ko ju ọgbọn iṣẹju lọ, ohun ti wọn si ṣe nibẹ ko ju pe wọn tu igbimọ adari ẹgbẹ naa, tawọn Oshiomhole, ka, wọn si yan igbimọ alaboojuto ti wọn fi Buni yii ṣe olori rẹ. Wọn paṣẹ pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ ko ẹjọ to wa ni kootu kuro kia, ọmọ APC kan ko gbọdọ pe ẹgbẹ naa tabi awọn adari rẹ lẹjọ kan mọ. Nigbẹyin, wọn ni ki igbimọ tuntun yii ṣeto ipade gbogbogboo, nibi ti wọn yoo ti yan awọn adari APC tuntun, laarin oṣu mẹfa pere. Nipade ba tuka o.

Yatọ si Buni ti wọn fi ṣe alaga igbimọ fidi-hẹ-ẹ yii, wọn mu Gomina Ọsun, Adegboyega Oyetọla, Gomina Niger, Abubakar Bello, lati fi ro igbimọ adari tuntun naa lagbara. Bi wọn si ti ṣepade naa tan ni Buni ti ko awọn ọmọ igbimọ naa lẹyin, o di ile ẹgbẹ wọn, kia lawọn ọlọpaa ti wọn ti tilẹkun ibẹ pa tẹlẹ sa kuro, awọn oloye ẹgbẹ tuntun naa si wọle. Ọrọ yii ko dun mọ awọn igbimọ adari to jẹ ti Oshiomhole ninu rara, wọn lawọn o gba, pe aṣẹ ti Buhari atawọn ti wọn jọ jokoo yii pa ko le mulẹ, ile-ẹjọ ni yoo ba wọn da a. Buhari ati ninu awọn gomina ti wọn jọ ṣepade gbagbọ pe ki i ṣe awọn ọmọ igbimọ naa lo n sọrọ, wọn ni Oshiomhole ni, wọn si ni ki i ṣe Oshiomhole paapaa lo n dun, Bọla Tinubu ni. Ṣe wọn ko kuku pe Tinubu sipade naa, wọn ni ko si ninu igbimọ apaṣẹ APC, bẹẹ ni ki i ṣe oloye ẹgbẹ, Asiwaju apapọ (National Leader) ti wọn n pe e, apọnle lasan ni, ko si oye naa ninu ofin ẹgbẹ wọn.

Ohun to je kawọn gomina yii mura lati gbomi ija kana pẹlu ẹni to ba ṣakọ ree, wọn si fi ọrọ si ẹnu adari agba ni ile ẹgbẹ awọn gomina APC, Salihu Lukeman, pe ọmọ ẹgbẹ yoowu, ni ipinlẹ yoowu to ba lọ sile-ẹjọ lẹyin aṣẹ ti Buhari ti pa yii, awọn yoo le e danu ninu ẹgbẹ awọn lẹsẹkẹsẹ ni. Wọn ni ofin ẹgbẹ lo faaye gba ohun ti Buhari ṣe: ti ija ba de laarin awọn ọmọ igbimọ adari ẹgbẹ wọn, ki igbimọ apaṣẹ agba jokoo lati pari ẹ, ipinnu yoowu ti igbimọ apaṣẹ agba yii ba si ṣe, kaluku ọmọ ẹgbẹ pata lo gbọdọ tẹle e, ẹni ti ko ba ti waa tẹle e wayi, ko ma ka ara rẹ kun ọmọ ẹgbẹ mọ o. Nibẹ ni pin-in-pìn-ìn-pin-in ti pin. Awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn n fapa janu tẹlẹ, kaluku bẹrẹ si i fori ara rẹ pamọ, wọn ko fẹẹ rija awọn gomina wọn, wọn ko si fẹẹ rija Buhari. Oshiomhole funra ẹ jade, o lọgun too, o ni oun ti fara mọ ipade awọn Buhari.

Alukoro igbimọ tawọn Oshiomhole yii tẹlẹ ni Isa Onilu, kia lo jade to ni gbogbo aṣẹ ti ijokoo awọn Buhari pa loun fọwọ si, oun si ti ṣetan lati duro ti igbimọ tuntun ti wọn gbe dide naa. Nigba ti oun ti le sọ eyi, ko si ẹni ti yoo sọrọ atako mọ. Bẹẹ lawọn igbimọ tuntun yii rẹyin ọta ti wọn rẹyin odi, ana ti i ṣe ọjọ aje ni wọn si ṣe ifilọlẹ wọn, iṣẹ si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu. Bo tilẹ jẹ pe Tinubu, Oshiomhole ati awọn ọmọlẹyin wọn n ṣe oju aye lori ọrọ igbimọ tuntun yii, sibẹ, wọn n binu labẹlẹ pe agbara lo bọ yii, wọn gba APC lọwọ awọn, gbogbo ohun ti wọn ti n to kalẹ lori bi Tinubu yoo ṣe dupo aarẹ lorukọ APC ni 2023 lawọn gomina ti wọn ko fẹran rẹ ti fọ bayii. Awọn gomina yii, ti El-Rufai jẹ olori pata fun nidii eto tuntun yii, ni wọn n paṣẹ APC bayii, ko si sohun ti wọn yoo fi lọ Tinubu mọ, ibi ti wahala si wa gan-an niyẹn.

Inu n bi Tinubu gan-an bayii, nitori lojiji ni kinni naa ba a; afi bii ala. Laarin wakati diẹ lọrọ yi biri, ko ro pe iru ẹ le ṣẹlẹ soun lae! O daro loju awọn to sun mọ ọn pe pẹlu gbogbo wahala ati inawo oun ninu APC lati ri i pe Buhari di aarẹ, ohun ti wọn waa fi san an foun niyi. Awọn ọmọlẹyin rẹ yii ni ko sohun to jọ ọ o! Wọn ni gbogbo ohun ba gba lawọn yoo fun un, lasiko ipade gbogbogboo lati yan awọn aṣaaju tuntun fun APC lawọn yoo ti duro de wọn, awọn yoo si ri i pe awọn gba ẹgbẹ naa pada lọwọ wọn. Nidakeji, bi ẹgbẹ yii ko ba ṣee gba, awọn yoo fọ ọ si wẹwẹ, lẹyin naa lawọn yoo pada sinu ẹgbẹ oṣelu awọn atijọ, ACN, tabi ki awọn da ẹgbẹ tuntun mi-in silẹ ti Aṣiwaju awọn yoo fi di aarẹ ni 2023. Itumọ eyi ni pe ọrọ naa yoo di ariwo rẹpẹtẹ, ija naa yoo si pọ, afaimọ ki wọn ma fa APC yii ya pẹrẹpẹrẹ bii aṣọ.

One thought on “Ọrọ yii ṣi maa dija: Wọn ti gba APC lọwọ Tinubu o

Leave a Reply