Ọsẹ keji ti wọn gba Emeka siṣẹ lo palẹ owo ọja wọn mọ l’Ekoo, Ibadan lo sa lọ

Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati aadọta Naira (N350,000), owo ọja ti wọn ta lo ti dawati nileeṣẹ burẹdi Tasty Loaf Bakery, l’Ekoo. Ọgbẹni John Emeka ti wọn ṣẹṣẹ gba siṣẹ lọsẹ meji sẹyin ni wọn lo palẹ owo naa mọ sapo ara ẹ, lo ba sa lọ.
Ọpẹlọpẹ kamẹra atanilolobo ti wọn ṣe sayiika ileeṣẹ burẹdi ọhun, eyi to wa lọna Ajelogo, lagbegbe Mile 12, nijọba ibilẹ Ikosi-Iṣheri, l’Ekoo, to ṣafihan bi Emeka ṣe n ka owo naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta to lọ yii, ọjọ naa si ni wọn ri i kẹyin.
Bi kamẹra naa ṣe fihan, gbogbo ẹru ẹ to wa nileeṣẹ naa lo ko lọ lọjọ yii, ṣugbọn o fi foonu ẹ silẹ, ko si siimu (Sim card) ninu foonu ọhun, o ti yọ ọ kuro, boya ki wọn ma le ṣewadii ẹ ni. Aago mẹfa ku iṣẹju mejila geere lo jade lọjọ naa.
Nigba ti wọn wa a ti wọn ko ri i, ti wọn o si ri owo ọja to ta, ni wọn lọọ fẹjọ ẹ sun ni teṣan ọlọpaa to wa ni Mile 12.
Oludari ileeṣẹ burẹdi ọhun, Abilekọ Motunrayọ Ọdunsi, sọ fun iweeroyin Punch pe: “Ile ounjẹ kan ni ọkọ mi ti pade Emeka, ibẹ lo ti n ṣiṣẹ, niṣe lo waa ba ọrẹ ẹ kan, Victor, tiyẹn o niṣẹ lọwọ bẹ ọkọ mi pe ka jọọ, ka ba oun gba a siṣẹ lọdọ wa.
“Ko ju oṣu kan lẹyin naa lọmọkunrin yii pe ọkọ mi lori aago pe wọn ti da oun duro nile ounjẹ toun ti n ṣiṣẹ, oun si n waṣẹ, o ni ka gba oun siṣẹ, la fi ṣaanu ẹ, a gba a siṣẹ.
Ko to ọsẹ meji ni Emeka tun waa ba wa pe ka jẹ koun maa gbe ile awọn oṣiṣẹ to wa ninu ọgba ileeṣẹ wa, o loun ni idojukọ ile gbigbe, la ba tun foju aanu han si i.
“Aarin asiko yẹn naa ni alagbata wa kọwe fiṣẹ silẹ, la ba kuku ni koun ṣi di ipo yẹn mu titi ta a fi maa gba ẹlomi-in tori ki i ṣe ohun ta a gba Emeka fun niyẹn. Akọsilẹ rẹ ko ti i peye lọdọ wa, ko si ti i kọ ọrọ kun fọọmu oniduuro rẹ.
“Ṣugbọn mo ranti pe ṣaaju asiko yii ni ọrẹ ẹ, Victor, ti kilọ fun ọkọ mi pe ka ṣọra pẹlu Emeka, o lo jale nibi tawọn ti kọkọ jọ ṣiṣẹ ni wọn fi le e danu, ṣugbọn ọkọ mi ro pe boya o fẹẹ ba a jẹ ni.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣiṣẹ iwadii, Ibadan ni wọn tọpasẹ afurasi naa de, o lọwọ maa to o laipẹ.

Leave a Reply