Ọsẹ yii nile-ẹjọ to ga ju lọ maa dajọ lori iyansipo Tinubu ati Shettima

Faith Adebọla

 Pẹlu bo ṣe ku ọsẹ kan pere ti wọn yoo ṣebura wọle fun aarẹ aṣẹṣẹ dibo yan ilẹ wa ati igbakeji rẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati Kashim Shettima, ko ti i si oorun asundọkan fawọn oloṣelu yii, latari bile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ṣe sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ta a wa yii, lawọn yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ nla kan ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), pe ta ko ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ati oludije funpo aarẹ wọn pẹlu igbakeji rẹ ninu eto idibo gbogbogboo to waye kọja yii.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022 to kọja, ni PDP ti wọ awọn mẹtẹẹta yii, iyẹn Tinubu, Settima ati APC, re kootu pe kile-ẹjọ wọgi le Shettima gẹgẹ bii oludije funpo igbakeji aarẹ, wọn lo ṣe lodi si iwe ofin eto idibo ilẹ wa, nitori iwe ofin naa ko faaye gba ki ẹni kan dije funpo meji ọtọọtọ lẹsẹ kan naa. Iru bi Shettima ṣe tọwọ bọwe idije funpo igbakeji aarẹ Naijiria ati ipo sẹnetọ ti yoo ṣoju awọn eeyan Aarin-Gbungbun ipinlẹ Borno lorukọ APC lasiko kan naa.

Wọn niwa ti Kashim Shettima hu yii, ati bi ẹgbẹ oṣelu rẹ naa, APC, ṣe faaye gba a, ta ko isọri kọkandinlọgbọn (29), isọri kẹtalelọgbọn (33), isọri karundinlogoji (35) ati isọri kẹrinlelọgọrin iwe ofin eto idibo nilẹ wa, ti ọdun 2022.

Ẹgbẹ PDP rọ ile-ẹjọ lati fa iwe iyasipo Shettima lati dije fawọn ipo yii ya, ki wọn si wọgi le bi APC ṣe yan wọn lati kopa ninu eto idibo naa, tori fifa ti wọn fa wọn kalẹ tẹ ofin loju gidi.

Ni ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja, nibi ti igbẹjọ naa ti kọkọ bẹrẹ, Adajọ Inyang Ekwo to wa lori  aga idajọ sọ pe ki PDP ma wulẹ laagun jinna lori ẹjọ yii, o ni ipinnu oun ni lati da ẹjọ ati ẹbẹ inu rẹ nu bii omi iṣanwọ, tori loju ofin, ẹgbẹ PDP ko lẹtọọ lati pe iru ẹjọ yii, ọrọ abẹle APC ni, ayọjuran lo si jẹ niwaju ile-ẹjọ pe PDP n da si ohun to n lọ ninu APC.

Idajọ yii ko tẹ PDP lọrun, ni wọn ba pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun sile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan niluu Abuja.

Igbimọ ẹlẹni-mẹta kan, eyi ti Onidaajọ James Abundaga, lewaju fun yiri gbogbo ọrọ ọhun ati atotonu tọtun-un tosi wo, wọn ni PDP ti i ṣe olupẹjọ yii ko ti i ṣalaye to tẹrun lori idi ti ile-ẹjọ fi gbọdọ gba wọn laaye lati rojọ lori awọn ẹsun ti wọn mu wa yii, wọn ni olujẹjọ ko kunju oṣuwọn to lati pe ẹjọ naa, wọn tun ni loju tawọn o, olooraye ti i ta kokoro f’eegun kan bayii ni wọn, wọn lọrọ abẹle ẹgbẹ APC kọ lo yẹ ki PDP maa ran-angun apa mọ.

Oju-ẹsẹ ni PDP ti palẹ iwe wọn mọ niwaju awọn agba onidaajọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn ni bẹru ba kọ oke, to kọ ilẹ, o ṣi nibi kan aa gbe e si ni tawọn o. Wọn ni irinajo awọn lori ẹjọ yii ko ti i tan, ile-ẹjọ to ga ju lọ ni yoo ba awọn da a, wọn si taari ẹjọ naa si wọn lai sọsẹ.

Latigba tẹjọ naa si ti dewaju ile-ẹjọ tẹjọ maa n pẹkun si yii ni olujẹjọ ati olupẹjọ ti n foju sọna fun ibi ti igi ẹjọ naa maa wo si. Ọjọbọ, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ni gbogbo wọn n reti bayii.

Leave a Reply