Osemawe ba awọn oloṣelu Ondo sọrọ, o ni ki won yee fibọn lera wọn kiri

Aderounmu Kazeem

Bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ṣe n koju ija sira wọn, ti wọn n yinbọn, ti wọn n ko idaamu ba araalu  bi eto idibo gomina ipinlẹ naa ṣe ku si dẹdẹ, Osemawe tilu Ondo, Ọba Victor Kiladejọ, ti pe wọn papọ bayii, bẹẹ ni wọn ti tọwọ bọwe wi pe alaafia yoo jọba.

Laipe yii ni Kabiyesi pe ipade ọhun, eyi ti oriṣiiriiṣi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa nikalẹ.  Lara awọn ẹgbẹ oṣelu to wa nibẹ lọjọ naa ni APC, PDP ati Zenith Labour Party.

Gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa nikalẹ lọjọ naa ni kabiyesi yii bẹ, ohun to si sọ ni pe ki wọn ma ṣe ta ẹjẹ ẹnikẹni silẹ niluu oun nitori ọrọ oṣelu.

Osemawe Ondo sọ pe, “Gẹgẹ bi baba ti mo jẹ fun kaluku yin, ko ni i dun mọ mi ninu lati padanu ẹnikeni nitori ọrọ oṣelu. Fun idi eyi, ẹ gbiyanju ki ẹ gba alaafia laaye, ki kaluku si tẹle ofin ati ilana ti ajọ eleto idibo la kalẹ.”

Niwaju ọba alaye yii naa ni awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta ti wọn lorukọ ju nipinlẹ Ondo ti tọwọ bọwe, wi pe awọn ko ni da ilu ru, bẹẹ lọmọ ẹgbẹ awọn kankan ko ni i da wahala silẹ lasiko ibo lọjọ Abamẹta, Satide to n bọ yii. Nibẹ naa ni ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa si fọwọ si i.

Tẹ o ba gbagbe, bo o lọ o yago lọrọ di lọjọ Satide to kọja yii nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP doju ija kọra wọn, ninu eyi ti ẹmi ti sọnu, ti ọpọ dukia bajẹ tawọn mi-in paapaa farapa yannayanna. Bẹẹ ni wọn ja ija ọhun titi di ana Sannde, ọjọ Aiku.

 

Leave a Reply