Ọshinọwọ ti dero ẹwọn o, owo ijọba lo ko jẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ibanujẹ ti wọn lo n dori agba kodo lọrọ da fun Ọgbẹni Stephen Ọshinọwọ nigba to n farahan niwaju adajọ ile-ẹjọ giga to n gbọ ẹsun akanṣe eyi to fidi kalẹ si Ikẹja, nipinlẹ Eko, pẹlu bi kootu naa ṣe taari oṣiṣẹ ọba ana naa satimọle ọgba ẹwọn, wọn lo ko ọtadinlaaadoje miliọnu Naira (127 million) owo ọba jẹ.

Ọgbẹni Ọshinọwọ ni akọwe agba tẹlẹ ri fun ẹka ileeṣẹ ọba to n ri eto ẹkọ-ọfẹ nipinlẹ Eko (Lagos State Scholarship Board.) Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku nni, EFCC, lo wọ ọ lọ sile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, wọn ni ko ṣalaye bi owo nla naa ṣe dawati nigba to fi wa nipo.

Ọkan ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọdaran naa ka pe: “Iwọ, Ọgbẹni Stephen Oshinọwọ, to o jẹ oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko huwa ainitiju nigba kan lọdun 2018, nigba to o sọ owo ti iye rẹ jẹ ọgbọn miliọnu Naira di nina fun Abilekọ Adenikẹ Ọshinọwọ, to o si mọ pe ẹka ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lo lowo ọhun.”

Ninu iwe ẹsun mi-in, wọn fẹsun kan afurasi naa pe o fọna eru lo ileeṣẹ aladaani kan ti wọn pe ni Julikam International Limited lati baana owo to din diẹ ni ogoji miliọnu Naira (N39,934,919.00) to jẹ ti ijọba ipinlẹ Eko, laarin ọjọ kẹjọ, oṣu keji, ọdun 2016, si ọgbọn ọjọ, oṣu kejila, ọdun kan naa. O si jẹ asiko tọkunrin ọhun wa nipo gẹgẹ bii akọwe agba ẹka ileeṣẹ ọba naa.

Agbejọro fun EFCC, Amofin Usman Buhari, ni alaye ti ko lori ti ko nidii, lafurasi naa ṣe nigba tawọn n ṣewadii, n lajọ naa fi wọ ọ dele-ẹjọ.

Nigba ti wọn beere lọwọ olujẹjọ boya o jẹbi tabi ko jẹbi, ọkunrin naa ni oun ko jẹbi pẹlu alaye.

Buhari rawọ ẹbẹ si kootu pe ki wọn mu ọjọ pato ti igbẹjọ ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa maa bẹrẹ, ki wọn si ma fun un ni beeli tori awọn ko fọkan tan an pe ko le sa lọ.

Ṣugbọn agbẹjọrọ olujẹjọ, Ọgbẹni Lawal Pedro bẹ ile-ẹjọ lati ma ṣe da akoko gigun fun igbẹjọ to kan, ki oun le raaye ṣeto lati bẹbẹ beeli fun onibaara oun, tori oun ẹsun ti wọn fi kan an ki i ṣe eyi ti ko le gba beeli fun.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo paṣẹ pe ki afurasi naa si lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, titi ti wọn fi maa kọkọ gbọ ẹbẹ rẹ fun beeli, ki igbẹjọ too bẹrẹ.

Leave a Reply