Oshiomhole jẹwọ: o ni, ọja buruku ni mo ta fẹyin ara Edo ni 2016

Ni gbangba waalia, GRA, ilu Binni ni olori ẹgbẹ APC tẹlẹ, Adams Oshiomhole, ti sọrọ naa nigba to n ba awọn ololufẹ APC sọrọ, nibi kampeeni ti wọn n ṣe nitori ibo gomina ti wọn yoo di ni ipinlẹ naa ninu oṣu kẹsan-an ọdun yii. Oshiomhole ni oun wa jẹwọ ni, niwaju gbogbo ọmo ipinlẹ Edo, pe ọja buruku loun ta fun wọn lasiko ibo 2016, ti oun fi sọ fun un pe Godwin Obaseki ni yoo ṣejọba ipinlẹ naa daadaa. O ni ki wọn ma binu soun o jare.

Loootọ, ni 2016, lasiko ti wọn yoo dibo gomina nibẹ, Obaseki lo jade lorukọ APC, Ize Iyamu si jade lorukọ PDP, Oshiomhole si ni gomina wọn. Lasiko kampeeni wọn, Oshiomhole ni ole, ọlẹ ati janduku ni Ize-Iyamu, nitori ẹ lawọn EFCC ṣe n wa a kiri, ati pe nigba ti oun mọ pe ole ni ni oun ko ṣe fi i ṣe kọmiṣanna, o ni to ba di gomina, yoo jẹ ipinlẹ Edo run ni. Oshiomhole ni oun fi Ọlọrun bura, Obaseki nikan loun mọ to le ṣe ipinlẹ wọn ko dara, ko tun si ẹlomi-in mọ rara.

Ṣugbọn ni ọdun yii, ija ti de laarin Oshiomhole ati Obaseki, Obaseki si ti wa ninu PDP, Ize-Iyamu si ti wa ninu APC, awọn mejeeji naa ni wọn si tun fẹẹ du ipo gomina, wọn kan yi ẹgbẹ oṣelu wọn pada ni. Eyi ni Oshiomhole ṣe n sọ pe ki wọn ma dibo fun Obaseki mọ, pe ki i ṣe eeyan daadaa, onijibiti ni, aṣiṣe loun ṣe ti oun ta iru ọja bẹẹ fun wọn, ṣugbọn ọja tuntun ti oun gbe de yii, iyẹn Ize Iyamu, ọrijina ni.

 

Leave a Reply