Ọṣun 2022: Bisi Akande fun Oyetọla ni ẹṣin, o ni ko gun un wọle agbara

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣẹnken ni inu gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ọṣun n dun nigba ti gomina tẹlẹ, Oloye Adebisi Akande, fa ẹṣin nla kan le Gomina Oyetọla lọwọ, to si sọ fun un pe “Gun un wọnu agbara”

Nigba ti gomina de ile Baba Akande niluu Ila, lasiko abẹwo to n ṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun, eleyii ti wọn pe akori rẹ ni “Mo ni yin lọkan ni gbogbo igba”, ni iṣẹlẹ ti wọn pe ni manigbagbe naa waye.

Abẹwo naa ni gomina n ṣe kaakiri awọn ẹkun idibo mẹṣẹẹsan an to wa nipinlẹ Ọṣun lati fi mọ awọn oloye ẹgbẹ tuntun, ati lati fi sọ erongba lati dupo gomina lẹẹkeji fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Gẹgẹ bi awọn lameetọ ninu oṣelu ṣe sọ, bi Baba Akande ṣe fun Oyetọla ni ẹbun ẹṣin nla naa nitumọ to jinlẹ, o si ṣafihan pe gbọingbọin ni adele alaga ẹgbẹ APC akọkọ ọhun wa lẹyin iṣejọba rẹ.

Wọn ni ẹṣin tumọ si agbara, ipa, ominira, iṣẹgun, okun, igboya ati ọgbọn, nitori ẹranko naa jẹ ẹyi to niyi pupọ laarin awọn ẹranko ti Eledumare da.

Gomina Oyetọla fi ẹmi imoore rẹ han si Oloye Akande fun ẹbun pataki naa, o si ṣeleri lati maa tẹsiwaju lati mu ori baba naa wu.

Saaju ni Ọrangun Ila, Ọba Wahab Oyedọtun, ti ṣeleri atilẹyin fun saa keji Gomina Oyetọla, o ni gbogbo ipa to wa nikawọ oun loun yoo ṣa lati mu un jawe olubori, nitori gomina ti ṣe daradara fun ilu Ila.

Leave a Reply