Osun APC: Arẹgbẹṣọla ko si nile, ni Oyetọla ba na an mọ wọọdu rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Pẹlu esi idibo to n wọle lọwọlọwọ bayii kaakiri wọọdu idibo to wa nipinlẹ Ọṣun, Gomina Gboyega Oyetọla lo da bii ẹni pe ibo rẹ n leke ju.

Ni Ileefẹ, Oṣogbo, Iwo, Ila, Ileṣa, Okuku, Iniṣa, Ilobu, Ijẹbu-Jeṣa atawọn ibomi-in ti Alaroye ti ri, bi Oyetọla ṣe n ṣe ipo kin-in-ni, ni Adeoti n ṣe ipo keji, ti Lasun si wa ni ipo kẹta.

Nigba ti a de wọọdu gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, iyẹn wọọdu kẹjo ni Ifọfin, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa, ibo ọọdunrun un o le mẹsan-an (309) ni Oyetọla ri, nigba ti Adeoti ri ibo aadoje o le mẹfa (146).

Ohun to waa jẹ kayeefi nibẹ ni pe ko si Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla nile lati dibo fun oludije to fa kalẹ, iyẹn Alhaji Moshood Adeoti.

Nigba ti alaga TOP ni wọọdu Arẹgbẹṣọla, Ọgbẹni Saheed Adegoke, n sọrọ, o ni aisi nile minisita naa lo jẹ ki oju awọn ri nnkan to ri lonii.

Adegoke ṣalaye pe latibi ayẹwo orukọ awọn oludibo loun ti ṣakiyesi pe eru ti wa nibẹ nitori ki i ṣe rẹgisita ti awọn lo nigba iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ ti awọn ṣe kọja ni wọn lo.

O ni ọpọlọpọ orukọ ni ko si nibẹ, nigba ti oun si beere lọwọ aṣoju ajọ INEC, ṣe lo sọ pe eyi ti wọn gbe fun oun niyẹn.

O fi kun ọrọ rẹ pe iye awọn ti wọn kọkọ ṣayẹwo orukọ wọn ko to iye awọn ti wọn to lori ila lasiko ti wọn fẹẹ dibo, bẹẹ ni awọn ti wọn ṣakoso idibo naa ko fun oun lanfaani lati buwọ lu esi idibo ti wọn kọ silẹ.

Leave a Reply