Faith Adebọla
Ayafi ki Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, to ṣẹṣẹ bẹrẹ saa keji nipo loṣu to kọja yii san ṣokoto rẹ girigiri pẹlu ẹjọ ti ọkunrin naa n jẹ ni kootu ti wọn ti n gbọ awọn ẹsun ati awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ ọhun. Idi ni pe alatako rẹ to pe e lẹjọ, Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, tawọn ololufẹ rẹ n pe ni Ladoo, tabi Ladi, ko mu ẹjọ ọhun ni kekere rara, awọn ẹlẹrii ti iye wọn to ọtalerugba ati mẹta (263) lolupẹjọ naa ni wọn ti wa ni ṣẹpẹ lati bẹrẹ si i jadi okoto irọ ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC) ati oludije funpo gomina labẹ asia All Progressives Congress (APC), pawọ-pọ tayo rẹ, toun yoo si fi han gbogbo aye pe Abiọdun ko wọle ibo nipinlẹ ọhun.
Yatọ si tawọn ẹlẹrii rẹpẹtẹ wọnyi, olupẹjọ ọhun to dije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, tun lawọn ni oniruuru iwe, akọọlẹ, sabukeeti ati ẹda iwe to ju ọgọta (60) lọ lati ko kalẹ niwaju igbimọ Tiribuna ọhun gẹgẹ bii ‘ẹri maa jẹ mi niṣo’ lati fi gbe awọn ẹsun tawọn mu wa lẹsẹ.
Ẹ oo ranti pe gbara ti ajọ INEC ti kede Dapọ Abiọdun bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo sipo gomina to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, pẹlu ibo to fi ẹgbẹrun mejila tayọ ti Adebutu, lọkunrin naa ti leri leka pe ikede ọhun ko le rẹsẹ walẹ niwaju ẹri ati ofin, o loun maa ba Abiọdun ati INEC fa a ni kootu ni, oun si ti ṣetan lati tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa pẹlu wọn, eyi lo mu kọrọ di ti Tiribuna.
Adebutu, nipasẹ lọọya rẹ, Amofin agba Goddy Uche, sọ niwaju igbimọ ọhun, lasiko ti igbẹjọ bẹrẹ lọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa yii, pe awọn ti gbaradi lati maa ko awọn ẹlẹrii awọn wa si kootu ni kẹtikẹti, tori wọn pọ. O ni Adebutu funra ẹ ni ẹlẹrii akọkọ, awọn ẹlẹrii yooku lawọn to si isọri isọri ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ, tawọn si fun ni awọn ẹgbẹ ẹlẹrii kọọkan ni ami idanimọ OGSC, AN1, AN2, AN3, AS4, AS5, AO6, AO7, IF9, IF10, SA95, OD98, VT99 ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan INEC ati Abiọdun, eyi ti wọn tori ẹ n rawọ ẹbẹ si tiribuna naa pe ko yọ Abiọdun nipo, ko si kede onibaara awọn, Adebutu ati ẹgbẹ oṣelu awọn, PDP, bii ojulowo oluyege ibo ni pe wọn ni adiju-ibo waye lawọn ibi kan, wọn ji apoti ibo gbe sa lọ lawọn ibomi-in, iwa jagidijagan ni wọn fi da ibo ru lawọn ibi kan ti wọn kede pe Abiọdun lo wọle nibẹ, wọn tun ni agbelẹrọ esi idibo ni INEC kọ lawọn ibi kan, ti wọn si tun diidi kọ ebe ibo rẹpẹtẹ fun APC ati Abiọdun lawọn ibudo idipo kaakiri awọn agbegbe kan, gbogbo ẹ pata si lawọn ti ṣawari rẹ.
Wọn tun mu ẹsun wa pe INEC, APC ati Abiọdun ko tẹle ilana ati alakalẹ ofin to rọ mọ eto idibo ọhun, gbogbo iwa irufin, ojoro, jibiti ati aṣilo agbara wọn lawọn si ti ṣetan lati tẹ pẹpẹ rẹ siwaju adajọ.
Koda wọn lawọn ti haaya ogbontarigi onimo-ijinlẹ, mọran-mọran ti i mọ oyun igbin ninu ikarahun, ati agba ọjẹ atọpinpin meji ti wọn yoo jẹrii ta ko awọn olujẹjọ naa.
Igbẹjọ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori ọrọ yii, ALAROYE yoo si maa fi to yin leti bi ọrọ naa ba ṣe n lọ si.