Ọlawale Ajao, Ibadan
Bi gbogbo ọmọlẹyin Jesu ṣe n gbadun ẹmi ara wọn fun ọdun Keresimesi to n lọ lọwọ, inu atimọle ọlọpaa n’Ibadan lọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun (18) kan, Fawas Popoọla Joshua, wa bayii pẹlu bi ọwọ awọn ọlọpaa ṣe tẹ ẹ lẹyin ti oun atọrẹ ẹ jọ fibọn gba baagi lọwọ onibaagi lojukoroju.
Ni nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii, ni Joshua pẹlu Umar Yesid, ọrẹ ẹ, lọọ na ibọn si ọmọbinrin kan to n jẹ Adeoti Bọlanle nigi imu ti wọn si gba baagi ati ẹrọ ibanisọrọ ọwọ ẹ nigba ti iyẹn n lọ sibi iṣẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira (N120,000) lo wa ninu baagi ti wọn fibọn gba lọwọ obinrin naa lọna ileewe aladaani kan ti wọn n pe ni Aliu Primary School, nitosi Isọ Pako, Bodija, n’Ibadan.
“Ṣugbọn nibi ti wọn ti n ṣa lọ ni wọn ti ko sọwọ awọn ọlọpaa to n lọ kaakiri agbegbe naa fun amojuto eto aabo. Bayii lawọn agbofinro mu awọn mejeeji tawọn tibọn ilewọ ti wọn fi digun jale naa”, bẹẹ ni alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọ.
SP Ọṣifẹṣọ, ẹni to ṣafihan awọn afurasi ọdaran mejeeji lorukọ CP Adebọwale Williams, sọ siwaju pe Joshua ati Umar ti fẹnu ara wọn jẹwọ nipa ẹsun naa pẹlu awọn idigunjale mi-in ti wọn ti ṣe ṣaaju.
Gẹgẹ bii iwadii ALAROYE, ọmọ bibi ilu Ibadan ni Joshua, adugbo Apẹtẹ, ti awọn obi ẹ kọle si ni gbogbo idile wọn n gbe. Fawas Popoọla lo fi silẹ lọdọ awọn ọlọpaa, ṣugbọn Joshua ti iya ẹ tẹ mọ ọn lara lawọn eeyan saaba maa n pe e nitori baba ẹ to jẹ Musulumi lo sọ ọ ni Fawas, nigba ti iya ẹ jẹ Kirisitẹni ti ki i fi ijọsin ni ṣọọṣi ṣere.
Ṣugbọn lati bii ọdun mẹta sẹyin ni Joshua, ẹni ti ko ti i to ọmọ ọdun mẹẹẹdogun nigba naa, ti sa kuro nile ti awọn obi ẹ fi owo oogun oju ara wọn kọ, to si n lọọ sun labẹ biriiji, niwaju ṣọọbu, labẹ ganta, tabi nibikibi to ba ti raaye fẹgbẹ lelẹ kaakiri agbegbe Mọkọla, n’Ibadan.
Ole to fẹran lati maa ja lati kekere naa lo le e kuro nile. Ọpọ igba lo ti dojuti awọn obi ẹ pẹlu ole to n ja yii, to jẹ pe lojoojumọ lo n rinhooho wọle nigba ti wọn ba ti lu u ja sihooho lẹyin to ba ti ji nnkan nile awọn ọrẹ ẹ, nile aladuugbo wọn, ati nibikibi to ba lọ.
Lẹyin ti itiju ko jẹ ko rile gbe mọ lo gba adugbo Mọkọla, nitosi Saabo lọ, n’Ibadan, nibi to ti bẹrẹ si i mugbo ati oniruuru egboogi oloro gbogbo pẹlu awọn ọmọ iṣọta ẹgbẹ ẹ ti iwa wọn bara wọn mu.
Mọkọla to n sun yii lo ti pade Umar ti wọn jọ n digun jale titi ti wọn fi ko si panpẹ awọn agbofinro.
Ni ti Umar, ọmọ ẹkọṣẹ telọ ni, Ibadan ni wọn bi i si, bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ipinlẹ Katsina lawọn obi ẹ. Ọkunrin ọmọọdun mẹtadinlogun yii le fa eefin sagbari lataaarọ dalẹ, siga mimu ni rai bii alafiṣe. Nitori eefin to kundun lati maa fa sagbari yii lawọn obi ẹ ṣe maa n lu u bii ẹni maa pa a, ṣugbọn to kọ ti ko yee fa siga.
Nigba to pade Joshua lo waa yayakuya tan pata nitori ti iyẹn kọ ọ niṣẹ adigunjale mọ iwa ipata to ti wa lọwọ ẹ tẹlẹ. Nibi ti awọn mejeeji ti ja foonu gba ninu ọja Bodija, gan-an ni wọn ti mu wọn.
Ọjọ kan pere ṣaaju iṣẹlẹ yii, iyẹn lọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila yii, kan naa, ni Bodija kan naa, ni wọn ti fibọn gba ẹrọ ibanisọrọ lọwọ ọmọ ẹgbẹ akọrin to n lọ si ṣọọṣi. Ko si ju wakati meji lọ lẹyin naa ni wọn ta foonu ọhun lẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn Naira (N25,000) ni Saabo, n’Ibadan.
Ninu owo ọhun ni wọn ti gba yara kan sileetura kan ta a forukọ bo laṣiiri laduugbo Mọkọla. Ileetura yii ni wọn si gba lọọ ja Omidan Bọlanle lole laaarọ kutu ọjọ Aje.
Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ siwaju pe ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (N15,000) ninu owo ti Joshua ati Umar ta foonu ti wọn kọkọ ji ọhun ni wọn pin laarin ara wọn, wọn fi ẹgbẹrun mẹrin Naira gba yara sileetura, nigba ti wọn fi ẹgbẹrun mẹfa Naira yooku gbadun ara wọn.
Ṣugbọn gbogbo faaji ti wọn ṣe ọhun nkọ, wọn ti n jiya rẹ lọwọ ninu atimọle awọn ọlọpaa n’Ibadan bayii. Afaimọ ni wọn ko si ni i foju bale ẹjọ nitori SP Ọṣifẹṣọ ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti seleri lati tanna wadii awọn mejeeji doju ami, ki wọn le jiya to ba tọ si wọn labẹ ofin.