Ounjẹ ọdun ni wọn ni ki Bimpe lọọ gbe fun Waheed, lo ba fipa ba a lo pọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lalẹ ọjọ ọdun Ileya to kọja, nigba ti gbogbo Musulumi ti n dupẹ pe Ọlọrun jẹ ki ọdun ọdun yii ṣoju ẹmi awọn, ẹkun lọmọdebinrin kan, Adebimpe, sun sùn mọju ọjọ keji. Ki i ṣe pe ẹnikan na an tabi febi pa a, bọọda kan laduugbo wọn, Waheed Ògúndélé,  lo fipa ba a laṣepọ.

Ounjẹ ọdun ni wọn ni ki Bimpe, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri lọọ gbe fun ọkunrin naa, Waheed Ogundele to jẹ alabaagbe wọn laduugbo Ologunẹru, n’Ibadan, lalẹ ọjọ naa (ọjọ Jimọ to kọja), n ni jagunlabi ba gba ounjẹ silẹ, lo ba fipa ba ọmọọlọmọ laṣepọ.

Lẹyin tọkunrin yii ti sa lọ mọ awọn ẹbi ọmọ naa nibi ti wọn ti n gbiyanju lati fa a le awọn agbofinro lọwọ, ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ ẹ, o si ti wa ninu ahamọ wọn bayii fun iwadii.

Mọlẹbi ọmọdebinrin naa to n jẹ Mahmud ṣalaye pe oun niya wọn sọ pe ko lọọ wo aunti ẹ wa nigba ti wọn ko tete ri i (Bimpe) ko de lati ibi ti wọn ran an, n loun ba pade ọmọbinrin naa to n sunkun bọ latinu ile Waheed. Njẹ ki lo ṣẹlẹ, o ni bọọda Waheed fipa ba oun laṣepọ.

Mahmud ṣalaye pe “Nigba ta a fẹẹ maa lọọ kirun  ni mọṣlalaṣi ni mo gbọ ti iya ẹ (Iya Bimpe) sọ pe ko lọọ gbe ounjẹ fun ẹnikan (Waheed). Wọn waa ni ki n lọọ wo o wa nigba ti ko tete pada de.

“Mo pade ẹ to n sunkun bọ, bẹẹ lẹjẹ n ṣan jade lati oju ara ẹ. Mo ni ki lo ṣe e, o ni Bọda Waheed lo fipa ba oun laṣepọ. Ṣugbọn awọn ọrẹ Waheed ko jẹ ka ri i mu, niṣe ni wọn fẹyin pọ ọn titi to fi sa lọ mọ wa lọwọ.

”Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fakọroyin wa, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe ‘ọwọ wa (awọn ọlọpaa) ti tẹ afurasi ọdaran naa, o si ti wa ni CID (ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iṣẹlẹ ọdaran) ni Iyaganku, n’Ibadan bayii.”

One thought on “Ounjẹ ọdun ni wọn ni ki Bimpe lọọ gbe fun Waheed, lo ba fipa ba a lo pọ n’Ibadan

  1. Eleyi yoo ko gbogbo awon ti ko gboran wipe ki a yee fi omobinrin ati omokunri n to ti balaga si arowoto Ara won lati dekun ifipabanilo, Olorun yoo run wa see ni ilu Yi

Leave a Reply