Ọwa Igbajọ, Ọba Fasade, ti waja

Bo tilẹ jẹ pe awọn Oloye ilu Igbajọ, nijọba ibilẹ Boluwaduro, nipinlẹ Ọṣun, ko ti i kede, sibẹ, arigbamu iroyin u fihan pe Kabiesi ilu naa, Ọba Olufẹmi Adeniyi Faṣade, Akẹran Kẹrin, ti waja.

 

Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, la gbọ pe baba naa jade laye ninu aafin rẹ lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.

 

Ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun 1990, ni baba naa gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ.

 

Ọga lẹnu iṣẹ ologun (Major) ni kabiyesi ko too darapọ mọ iṣẹ ẹnjinnia latibi ti idile rẹ ti fa a kalẹ gẹgẹ bii ọba.

 

Leave a Reply