Ọwa Obokun ki Oyetọla laya: Fọkan balẹ, saa keji rẹ ti daju

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọba (Dokita) Gabriel Adekunle Aromọlaran, Ọwa Obokun ti ilẹ Ijeṣa, ti ki Gomina Gboyega Oyetọla laya pe oun nikan ni oludije ti gbogbo ilẹ Ijeṣa yoo dibo fun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii.

Ọwa tẹnumọ ọn pe asiko idibo yii lawọn yoo san oore bi Oyetọla ṣe ka ilu naa si fun un, ati pe ki ẹnikẹni ti ko ba dun mọ pe ki gomina ṣe saa keji lọ fori sọlẹ.

Lasiko abẹwo ti gomina ṣe si ẹkun idibo Guusu Ijeṣa ni Ọba Aromọlaran sọrọ naa laafin rẹ. O ni gẹgẹ bii ori-ade, ẹnu oun ka awọn araalu oun, ohun ti oun ba si sọ fun wọn ni wọn yoo ṣe.

O ni ọkẹ aimọye awọn oludije le wa lati fi erongba tiwọn naa han, Oyetọla ni gbogbo awọn ọmọ ilẹ Ijeṣa lọkunrin ati lobinrin yoo dibo fun nitori oun lawọn fontẹ lu.

Ọwa Obokun fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹ ọwọ Oyetọla ti to lati polongo ibo fun un, paapaa, ipa to n ko lati ri i pe alaafia n jọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.

Kabiesi ni, “A ko faaye gba janduku niluu Ileṣa, a ti kilọ fun gbogbo awọn ọmọ wa lati yago fun iwa to le da omi alaafia ilu ru. Ibo alaafia lawa fẹẹ di fun gomina.

“Gbogbo wa pata la wa fun gomina, mo si mọ pe gomina naa wa fun wa. A maa dibo yẹn daadaa. Bi wọn ba ka ibo yẹn lẹẹmẹwaa, Oyetọla lo maa wọle ni Ileṣa nitori a ki i ṣe abaramoorejẹ”

Leave a Reply