Ọwọ Amọtẹkun tẹ Amọdu, awọn Fulani ẹgbẹ ẹ lo ji gbe l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹṣọ Amọtẹkun tun ti ṣe aṣeyọri mi-in ninu akitiyan wọn lori gbigbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Ondo pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ ọkan ninu awọn ogbontarigi ajinjgbe to n yọ awon eeyan agbegbe Akoko lẹnu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọkunrin to porukọ ara rẹ ni Amọdu Seke ọhun nikan lọwọ ṣi tẹ ninu ikọ ajinigbe ẹlẹni meje ti wọn ṣiṣẹ ibi ni Ajọwa Akoko ati agbegbe rẹ.

Awọn meji ni wọn ba ninu igbekun awọn ajinigbe naa lasiko ti wọn tọpasẹ wọn lọ sinu igbo ti wọn fi ṣe ibuba.

Ninu iwọnba ọrọ diẹ to ba awọn oniroyin sọ, afurasi ọdaran ọhun ni loootọ loun ko niṣẹ méjì ti oun waa ṣe nipinlẹ Ondo ju iṣẹ ajinigbe lọ.

Fulani ọhun ni agbegbe Benin, nipinlẹ Edo, lawọn ti n ṣiṣẹ ajinigbe tẹlẹ ki awọn too kọja siluu Okene, nipinlẹ Kogi, nibi tawọn gba wọ ipinlẹ Ondo.

O ni meje lawọn, bo tilẹ jẹ pe oun nikan ni wọn ṣi ri mu. Amọdu ni o lawọn ti oun n ṣiṣẹ fun nitori pe iṣẹ ajinigbe gan-an ni wọn tori rẹ ko awọn wa si ipinlẹ Ondo.

Bakan naa lo tun jẹwọ pe eeyan meje lawọn ji gbe lọjọ kan ṣoṣo ki awọn ẹṣọ Amọtẹkun too waa fi pampẹ ofin gbe oun.

Awọn meji ti wọn gba silẹ lọwọ awọn ajinigbe ohun, Musa Ibrahim ati Amidu Ibrahim ni ibi tawọn ti n daran ni wọn ti ji awọn gbe, wọn fokun de wọn lọwọ sẹyin, bẹẹ ni wọn paṣẹ fun awọn lati tete pe awọn eeyan awọn ti yoo waa sanwo itusilẹ wọn.

Wọn ni oorun ti Amọdu n sun lọwọ lasiko tawọn Amọtẹkun de lọwọ fi tẹ ẹ nigba tawọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ raaye sa lọ.

Alakooso agba fun ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni afurasi tọwọ tẹ naa ti n ka boroboro, to si ti ṣalaye awọn ọna tọwọ yoo fi tẹ awọn ikọ ajinigbe yooku laipẹ.

Adelẹyẹ ni ki i ṣe ẹya Yoruba nikan lawọn agbebọn naa n ji gbe nitori pe ẹya Fulani kan naa ni Amidu ati Musa ti ori ko yọ lọwọ wọn.

O ni Supare Akoko ni wọn ti ji awọn mejeeji gbe, ti wọn si fipa gba ọpọlọpọ nnkan lọwọ wọn, nigba to ku dẹdẹ ki wọn pa wọn lo ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun ja lu wọn ni ibuba wọn, ti wọn si tu wọn silẹ kuro ninu igbekun wọn.

Leave a Reply