Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn obinrin mẹrin lori fifọmọ ṣowo ẹru lọ si orilẹ-ede Libya.
Awọn obinrin mẹrin naa ni: Dorcas Adefowokẹ, Oyetunji Ẹbunoluwa, Adefowokẹ Toyin ati Boluwatifẹ Ṣorẹmi. Meji lara wọn jẹ ojisẹ Ọlọrun, ti wọn si ni ileejọsin tiwọn ni Ado-Ekiti ati Igbimọ-Ekiti.
Ọkan lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun meji naa sọ pe oun ti ko ọmọdebinrin ti ko din ni ọgbọn kọja si orile-ede Libya.
Nigba ti wọn n ṣe afihan awọn ọdaran mẹrin naa, ọga ẹṣọ Amọtẹkun l’Ekiti, Birigedia Joe Kọmọlafẹ, sọ pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa lẹyin ti awọn araalu kan ta awọn lolobo lori ọrọ naa.
O ṣalaye pe itọpinpin awọn Amọtẹkun naa fihan pe awọn ọdaran ọhun ti pari gbogbo eto lati ko awọn ọmọ obinrin naa lọsi orilẹ-ede Lybia lai sọ fun awọn obi wọn.
O ṣalaye pe awọn awọn obinrin naa ti gbera lati Ado-Ekiti lati lọọ ko wọn fun awọn alagbata miiran ti yoo ko wọn kọja si orile-ede Lybia, ki ọwọ Amọtẹkun too tẹ wọn.
O ṣalaye pe awọn ọdaran naa ti jẹwọ wọn fun ajọ to n gbogun ti fifọmọ ṣe owo ẹru ati lilo ọmọ nilokulo, National Agency for the Prohibition (NAPTIP), ti wọn si ti ko wọn lọ si olu ileeṣẹ wọn.
Nigba ti awọn oniroyin n fi ọrọ wa awọn ọmọdebinrin naa lẹnu wo, wọn ṣalaye pe awọn ọdaran naa ni wọn ṣeleri pe wọn yoo ran wọn lọwọ lọ si ilu oyinbo.
Ọkan lara awọn ọmọdebinrin naa torukọ rẹ n jẹ Shorimu Boluwatifẹ, ṣalaye pe oun sa kuro nile nitori pe ẹgbọn oun ti oun n gbe ni ọdọ rẹ n fi ipa ba oun lo pọ.
O ni ni kete ti oun sa kuro nile ni oun ṣalabaapade obinrin kan to ni ile ijọsin, to si ṣeleri pe oun yoo mu oun lọ si ilu oyinbo, ti oun si gba lati duro ti i.
O fi kun un pe okunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Okiki lo mu wọn lọ si ọdọ iya rẹ to jẹ oludasilẹ ijọ ni Igbima-Ekiti, ti oun naa tun ṣeleri pe oun yoo ba awọn ṣeto lati mu oun lọ si ilu oyinbo.
‘’Oun gan-an lo ko wa si ọkọ to gbe wa lọ si Warri, ibẹ la ti pade obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Lizzy, to gba wa sọdọ fun ọjọ meji ko too ko wa lọ si Jalingo, ki awọn Amọtẹkun too gba wa silẹ.