Ọwọ awọn Amotẹkun ti tẹ awọn Fulani ajinigbe ti wọn n kogun lọ si Ibarapa o
Awọn Fulani kan ti won fura si pe ajinigbe ati ọdaran ni wọn ti bọ sọwọ bayii o. Awọn Amotẹkun lo mu wọn. Odidi mọto kan ni wọn gbe, mọto agbarigo, wọn si kun inu rẹ bamubamu.
Ibarapa ni wọn sọ pe awọn n lọ, o si daju pe wọn n fẹẹ lọọ maa huwa ọdaran wọn nibẹ ni, nitori ibọn mẹẹdọgbọn, ati aja nla nla mẹwaa ni wọn ba lọwọ wọn. Mọto kan lati ipinlẹ Kebbi ni wọn fi ko awọn Fulani oniwahala yii, nọmba moto naa si ni TUR30ZY.
Nibi ti wọn ti n bọ lawọn Amọtẹkun ti Gbenga Ọlanrewaju ṣaaju wọn ti da wọn duro ni agbegbe Ido, nigba ti wọn ko ri alaye gidi kan ṣe. Wọn ti ko awọn ọdaran Fulani yii le awọn ọlopaa lọwo, nibi ti wọn yoo ti le ṣalaye ohun ti won n wa lọ si agbegbe Ibarapa, nibi ti awọn ara wọn ti n ji awọn eeyan gbe lojoojumọ.