Ọwọ awọn ọdẹ ibilẹ tẹ ajinigbe meji l’Ekiti, wọn tun gba owo ti wọn ba lọwọ wọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọwọ agbarijọpọ awọn ẹṣọ ti wọn n sọ ẹnubode ipinlẹ Kogi ati Ekiti, ti tẹ meji lara awọn ajinigbe ti wọn ji ọga agba ileewe girama kan, olukọ meji ati oṣiṣẹ eleto ìlera kan gbe nipinlẹ Ekiti.

Agbarijopo ẹṣọ naa ti awọn ṣọja, ọlọpaa, Amọtẹkun ati awọn ọdẹ ibilẹ wa laarin wọn ni wọn da silẹ ni agbegbe naa lati gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe to n waye leralera ni agbegbe naa.

Lẹyin ti wọn mu meji lara awọn ọdaran naa ni wọn tun ri owo to to bii miliọnu mẹta gba pada lara owo ti wọn ti gba lọwọ awọn ti wọn ji gbe naa.

Ọga agba ileewe girama kan ati awọn olukọ meji pẹlu oṣiṣẹ eleto ilera kan ni awọn ajinigbe naa ji gbe ni Irele-Ekiti, nijọba ibilẹ Ajọni, nipinlẹ Ekiti, ni opin ọsẹ to kọja yii, ti wọn si ko wọn lọ si ibi ti ẹnikan ko mọ.

Mẹta lara awọn ti wọn ji ko naa ni wọn yọnda wọn lẹyin ti wọn gba miliọnu mẹta Naira lọwọ wọn. Ọkan lara awọn ti wọn ji ko naa mori bọ lọwọ awọn ajinigbe naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alaga ijọba ibilẹ Onitẹsiwaju Àjọni, Ọnarebu Michael Ogungbemi, ṣalaye fawọn oniroyin ni Ado-Ekiti, pe ọwọ tẹ awọn ajinigbe naa ninu igbo kan ni ẹnubode ipinlẹ Kogi pẹlu iranlọwọ agbarijọpo ẹṣọ agbegbe naa.

O sọ pe akitiyan awọn ẹṣọ naa lo fa a ti awọn ajinigbe ọhun fi sare yọnda awọn ti wọn ji gbe naa, eleyii to fun awọn ẹṣọ naa laaye lati tọpinpin wọn ninu igbo naa ki ọwọ too tẹ wọn.

“Ni kete ti wọn ri i pe awọn ẹṣọ naa ti fẹẹ kan wọn lara ni wọn sare yọnda awọn ti wọn ji ko naa. Bakan naa ni ọwọ tẹ meji lara awọn ajinigbe ọhun, ti wọn si gba owo ti wọn ti gba lọwọ awọn eeyan pada.

Awọn ti wọn ji gbe naa ti wa nileewosan aladaani kan ni Ikọle-Ekiti, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọlọwọ.

Ṣugbọn ọga awọn Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe loootọ ni ọwọ awọn tẹ meji lara awọn ajinigbe naa. O ni awọn meji tọwọ tẹ naa ti wa ni akolo ọlọpaa, nigba ti awọn ti wọn tu silẹ naa ti n ngba iwosan lọwọ.

Leave a Reply