Ọwọ ba Akibu, olori ẹgbẹ okunkun tawọn ọlọpaa n wa l’Ogijo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Olori ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ ni wọn pe ọkunrin kan, Akibu Takare, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26), o si ti pẹ tawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede rẹ pe awọn n wa a nitori awọn iwa ọdaran. Afi bi ọwọ wọn ṣe ba a lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, nibi to ti n jale lọwọ l’Ogijo.

Ẹnikan lo pe DPO teṣan Ogijo, Muhammed Suleiman Baba, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ naa pe awọn kan n jale lọwọ lagbegbe Gbaga ati Kamalu, l’Ogijo.

Eyi lo mu DPO naa ati awọn fijilante kora wọn jọ, wọn lọ sibi ti ikọ adigunjale ọhun ti n gba dukia awọn eeyan, ti wọn n pa wọn lẹkun.

Nigba ti Ọlọrun yoo ṣe e, Akibu Takare ti wọn ti n wa tipẹ lọwọ ba, awọn yooku rẹ ti wọn jọ n ṣọṣẹ lọwọ sa lọ ni.

Akibu funra ẹ jẹwọ pe Ikorodu loun atawọn ẹgbẹ oun naa ti waa jale l’Ogijo, diẹ ninu awọn to si pitu fun lalẹ ọjọ tọwọ ba a yii tọka rẹ pe bo ti gbowo lọwọ awọn lo gba foonu atawọn nnkan ini awọn mi-in.

Ibọn ilewọ ibilẹ ẹlẹnu meji ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, sọ pe awọn ba lọwọ rẹ.

Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ yii, CP Edward Ajogun, ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn adigunjale yooku to sa lọ ninu ẹgbẹ Akibu yii ri, ki wọn si gbe oun ti ọwọ ba naa lọ sẹka ti wọn yoo ti fọrọ wa a lẹnu wo si i lori aṣemaṣe ẹgbẹ okunkun ati awọn idigunjale to ti ṣe.

Leave a Reply