Ọwọ ba Inpẹkitọ atawọn ọrẹ ẹ ti wọn n f’aṣọ EFCC lu jibiti l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Bọwọ ṣe ba awọn afurasi ọdaran mẹta to n forukọ ileeṣẹ EFCC lu jibiti l’Ekoo fi han pe wọn diidi mu iṣẹ gbaju-ẹ naa niṣẹ gidi ni, tori aṣọ pupa bii ina tawọn ẹṣọ ajọ naa maa n wọ ni wọn ba lọrun wọn, bẹẹ ni wọn ṣe ayederu kaadi idanimọ ajọ naa.

Ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Ghali Mohammed Ahmed, lo sọrọ lorukọ ọga ẹ, AbdulRasheed Bawa, o ni Ọjọruu, Wẹsidee, lọwọ ba awọn mẹta kan ti wọn n pera wọn ni oṣiṣẹ ajọ EFCC, Pascal Ugwu Chijoke ati Sodiq Ibrahim Adekunle, pẹlu ẹni kẹta wọn toun jẹ inspẹkitọ ọlọpaa, Edwin Bassey. Agbegbe Lẹkki, ninu New Horizon Estate lọwọ ti ba wọn.

Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe ri wọn mu, Ahmed ni niṣe lawọn afurasi ọdaran naa ya bo ile ẹnikan ninu ẹsiteeti ọhun pẹlu ayederu aṣọ EFCC ati kaadi idanimọ wọn, wọn bẹrẹ si i ko ṣibaṣibo ba ọnitọhun, wọn ni ko maa ṣalaye owo to wa ninu akaunti ẹ fawọn ati bo ṣe rowo ra ile to n gbe naa, tori iwe ẹsun rẹ ti de iwaju ọga awọn.

Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nitori ẹni ti wọn lọọ halẹ mọ lati ṣe gbaju-ẹ fun ọhun lo dọgbọn tẹ ileeṣẹ EFCC Eko laago, bii ọgan si lawọn agbofinro ti de’bẹ.

Gbara ti gbangba ti dẹkun, ti kedere si ti bẹ ẹ wo mọ awọn afurasi ọdaran naa lọwọ, wọn fẹẹ gbọna ẹyin sa lọ, ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro ni wọn bọ si, wọn si fi pampẹ ofin gbe wọn.

Wọn ni bi wọn ṣe mu wọn ni Inpẹkitọ Bassey ti bu sẹkun, o loun ko wa ri, pe wọn ṣẹṣẹ pe oun lọ oko jibiti ọhun ni, o lọdun mẹrindinlogun oun toun ti wa lẹnu iṣẹ ọlọpaa ree.

Ṣa, Ahmed ni awọn ti fa gbogbo wọn le awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ, iwadii si n tẹsiwaju lori wọn.

Ahmed tun lo anfaani naa lati sin awọn araalu ni gbẹnrẹ ipakọ pe ki wọn beere awọn ẹri idanimọ to yẹ ati iwe ifaṣẹ-ọba-mu-ni (warrant of arrest) lọwọ oṣiṣẹ ajọ EFCC to ba dunkooko mọ wọn, ki wọn si tete ta ileeṣẹ naa tabi awọn agbofinro lolobo ti wọn ba fura si iwa arumọjẹ eyikeyii lọwọ ẹnikẹni to pera loṣiṣẹ EFCC.

Leave a Reply