Ọwọ ba Sanni Gafar, afurasi afẹmiṣofo to mura bii obinrin n’Ijọra

Monisọla Saka

Ori lo ko Sanni Gafar, ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), kan yọ lọwọ awọn eeyan agbegbe Ijọra Badia, nipinlẹ Eko, nigba ti wọn ṣuru bo o, ti wọn si fẹsun afẹmiṣofo kan an.

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa ti wọn gba a kalẹ lọwọ awọn eeyan tinu n bi naa ki wọn too lu u pa.

Lọjọ Aje, Mọnde, ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lori ẹrọ alatagba Twitter rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni, “Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ oni, awọn ero ṣuru bo ọkunrin kan ti wọn fura si pe o jẹ afẹmiṣofo lagbegbe Ijọra Badia.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa tete debẹ, wọn si gba ọkunrin naa lọwọ awọn ero ki wọn too gbẹmi lẹnu ẹ.

“Iwadii ta a ṣe fihan pe orukọ ọkunrin afurasi yii, ti ọpọlọpọ wọn sọ pe o dibọn, to si mura bii obinrin ni Sanni Gafar, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn.

Wọn ka baagi kan mọ ọn lọwọ to ko awọn nnkan bii haama(hammer)  mẹta, sukudiraifa (screwdriver) mẹfa, pulaya(plier), sisu(chisel) sipana(spanner) marun-un, waya, ṣokoto dudu kan, paali ti kiliipu wa ninu ẹ atawọn nnkan mi-in to jẹ mọ iṣẹ awọn mẹkaniiki ni wọn ba lọwọ.

“Ṣugbọn iwadii ṣi n tẹsiwaju lati fidi ọrọ rẹ mulẹ gẹgẹ bo ṣe sọ pe oṣiṣẹ onina mọnamọna (electrician) loun.

Nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi, n gboriyin fawọn olugbe Eko fun iwa oju lalakan fi n ṣọri ti wọn hu ọhun, o ki wọn nilọ lati ma ṣe ma ṣe idajọ lọwọ ara wọn.

O ni ki wọn maa gba teṣan ọlọpaa tabi ti awọn ẹṣọ alaabo mi-in lọ lati fẹjọ ẹnikẹni ti irin ẹsẹ rẹ tabi ti ihuwasi rẹ ba mu ifura dani sun, o si rọ wọn lati wa ni imurasilẹ nigba gbogbo ni ayika wọn”.

Leave a Reply