Ọwọ ba Sọdiq, awọn akẹkọọ-binrin lo maa n digun ja lole lositẹẹli wọn ni n’Ipara Rẹmọ

Gbenga Amos

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun, owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan tọwọ ọlọpaa tẹ nibi to ṣubu si lẹyin to ti fara gbọta, nigba toun ati awọn adigunjale ẹlẹgbẹ rẹ n ja awọn akẹkọọ-binrin lole ni ile ti wọn n gbe n’Ipara Rẹmọ, ipinlẹ Ogun.

Ọjọbọ Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta yii, ni DPO awọn ọlọpaa to wa ni ẹka ileeṣẹ wọn to wa n’Iṣara gba ipe pajawiri pe awọn adigunjale bii mẹfa n ṣọṣẹ lọwọ fawọn akẹkọọ-binrin nile ti wọn n gbe, kidaa awọn obinrin lo si wa ni ile wọn ọhun.

Loju-ẹsẹ ni DPO naa, CSP Oluwatosin Ṣobiyi, ti ṣeto ki ikọ ọlọpaa lọọ koju awọn apamọlẹkun-jaye ẹda naa.

Bi wọn ṣe debẹ, gẹgẹ bi alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe ninu atẹjade to fi lede lori ọrọ yii, o lawọn adigunjale naa gbena woju awọn ọlọpaa, wọn bẹrẹ si i yinbọn mọ wọn, lawọn ọlọpaa naa ba fibọn da wọn lohun.

Wọn lọwọ ibọn awọn ọlọpaa naa ro ju tiwọn lọ, ọpọ lara wọn lo si fara gbọta, ni wọn ba bẹ lugbo to wa lẹyin ọgba ile naa, wọn sa lọ. Awọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, wọn n le wọn lọ.

Nibi ti wọn ti n wa wọn ninu igbo ni wọn ti ri afurasi ọdaran yii, Sọdiq nibi to ṣubu lulẹ gbalaja si, oro ibọn ti mu un, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.

Wọn lawọn ọlọpaa wa inu igbo naa, ṣugbọn wọn ko ri awọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku, ṣugbọn wọn ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ sigboro lati mu awọn to sa lọ ọhun.

Ṣa, awọn ọlọpaa gbe e sẹyin ọkọ wọn, o si ti wa lẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ, nibi to ti n ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii.

Leave a Reply