Ọwọ ba Sugar ati Stainless ni Mushin, ibọn ni wọn fi n digunjale

Faith Adebọla, Eko

Awọn afurasi adigunle meji kan, Quadri Ayọnuga ti inagijẹ rẹ n jẹ Ṣuga, ati Shẹriff Ṣonibarẹ, Stainless ni wọn mọ oun si. Awọn mejeeji ti balẹ sahaamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, wọn ti n ṣalaye bi ibọn ṣe dọwọ wọn ati ọṣẹ buruku ti wọn ti fibọn ṣe.

Awọn ọlọpaa o ṣadeede mu Stainless ati Ṣuga, afurasi ọdaran kan, Peter Arinọla, ti inagijẹ tiẹ n jẹ Blood lo darukọ awọn mejeeji yii fawọn ọtẹlẹmuyẹ to n wadii ọrọ wo lẹnu ẹ, o lawọn jọ n ṣiṣẹ adigunjale ni, lawọn ọlọpaa fi bẹrẹ si i wa wọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu keji yii, ni ọwọ ba Peter nibi to ti yọbọn si aṣẹwo kan to fẹẹ fipa ba sun lọfẹẹ, konitọhun too lọgun sita, tawọn ero fi pe le wọn lori, ti wọn si fa ohun ati ibọn ọwọ ẹ le ọlọpaa lọwọ lẹyin ti wọn ti din dundu iya fun un. Lẹnu iṣẹ iwadii yii ni wọn ni Peter ti darukọ awọn tọwọ ṣẹṣẹ ba yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, to sọ nipa iṣẹlẹ yii f’ALAROYE pe latigba ti wọn ti darukọ Ṣuga ati Stainless lawọn ti n dọdẹ wọn, ṣugbọn wọn ko ri wọn mu. O ni ibi tawọn ọlọpaa Surulere ati Idimu ti n da awọn eeyan duro lati yẹ ara wọn wo lọwọ ti ba awọn afurasi ọdaran naa lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, lẹyin tawọn ti gbọ finrin pe o daa bii pe wọn wa laduugbo Mushin.

Ibọn oyinbo meji ati ọta ibọn rẹpẹtẹ ni wọn ba lapo wọn, wọn tun ka egboogi oloro mọ wọn lọwọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe kawọn mejeeji maa lọ sọdọ ẹni kẹta wọn ni Panti, gbogbo wọn ti n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Leave a Reply