Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lẹyin ọsẹ kan ti ikọ ẹlẹni mẹrin kan ya wọ Ijohun, nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ti wọn pa mama kan, Hannah Suberu, tawọn eeyan mọ si Iya. Maria, awọn fijilante So-Safe ti ri ọkan ninu wọn ti wọn pe orukọ ẹ ni Sunday Ishola, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) mu.
Abule Oguba, lorilẹ-ede Olominira Benin, lọwọ ti ba Sunday lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Ogunjọ, oṣu kẹjọ, ni Sunday atawọn mẹta mi-in gun ọkada wọ Ijohun, nigba to ku die ki aago mejila oru lu, ile Iya Maria ni wọn ṣigun lọ.
Wọn gbe Maria atọmọ to n tọ lọwọ lọ loju iya ẹ, n niya naa ba bẹrẹ si i pariwo pe kawọn araadugbo gba oun. Nibi to ti n sunkun, to n kigbe, naa ni awọn ajinigbe yii ti yinbọn lu u bi Alukoro So-Safe, Mọruf Yusuf, ṣe sọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ri Maria atọmọ ẹ gba pada pẹlu iranlọwọ awọn So-Safe yii, Hannah Suberu ti i ṣe Iya Maria ti ku iku ọmọ ti i pa Ayitalẹ.
Ileri ikọ fijilante yii lati mu awọn to ṣiṣẹ ibi naa lo gbe wọn de Ilẹ Olominira Benin, nibi ti wọn ti ri Sunday Ishola mu. Wọn ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ bayii ni Naijiria, awọn iyẹn ni yoo maa tẹsiwaju ninu iwadii ati itọpinpin, ti wọn yoo si gbe e lọ sile-ẹjọ.