Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun tẹ awọn Fulani meji to rufin ifẹranjẹko l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe awọn Fulani meji ti wọn ṣẹ sofin ifẹranjẹko lọna aitọ.

Awọn afurasi ọdaran ọhun, Abdullahi Sanni ati ẹgbọn rẹ, Baba, lọwọ tẹ lagbegbe Iju, nijọba ibilẹ Ariwa, Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Alaye ti Oloye Adetunji Adelẹyẹ to jẹ oludari ẹṣọ alaabo naa ṣe fun wa ni pe awọn darandaran ti awọn mu ọhun ti ṣẹ sofin nipa fífi nnkan ọṣin wọn ba ire oko awọn agbẹ kan jẹ.

O ni awọn ti ṣetan lati maa fi eyikeyii tọwọ ba ti tẹ ninu awọn darandaran ọhun jofin nitori pe ohun ti ko bojumu rara ni bi wọn ṣe kọ lati ka ofin tuntun ti Gomina Akeredolu ṣẹṣẹ buwọ lu naa si.

Adelẹyẹ ni ọjọ meji sẹyin lawọn sì fi panpẹ ofin gbe awọn Fulani mẹta pẹlu maaluu bii ọgọsan-an lori ẹsun yii kan naa.

Ọkan-o-jọkan ipade lo ni awọn ti ṣe pẹlu ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ Miyẹti Allah nipinlẹ Ondo fun bo ṣe fẹẹ bawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ sọrọ, ko si lawọn lọyẹ lori pataki ati anfaani to rọ mọ ofin tuntun naa, ṣugbọn to jẹ pe kaka kewe agbọn rọ, pipele lo tun n pele si i.

Oludari ẹsọ Amọtẹkun ọhun ni ẹbẹ lawọn Fulani ọhun maa n bẹ lọpọ igba tọwọ ba tẹ wọn lori ẹsun ṣiṣe lodi sofin ti awọn si maa n fun wọn lanfaani ati san owo itanran fun awọn ti wọn ba ba nnkan ọgbin wọn jẹ.

O ni ijiya to kere ju fun ẹnikẹni to ba ti ṣẹ si ofin ifẹranjẹko ipinlẹ Ondo ni ẹwọn ọdun mẹta tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira gẹgẹ bii owo itanran.

Oloye Adelẹyẹ ni awọn ti kilọ fawọn darandaran to wa nipinlẹ Ondo pe ko si aaye fun dida ẹran lati ibi kan lọ si ibomiiran mọ gẹgẹ bi wọn ti n ṣe tẹlẹ, o ni awọn ti sọ fun wọn ki wọn maa ko awọn ẹran wọn sinu ọkọ nigbakuugba ti wọn ba fẹẹ kuro nibikan lọ sibomi-in.

Leave a Reply