Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun tẹ Alfa to n ji ẹran agbo l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Owolabi lorukọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ọhun, ṣugbọn Alfa ni inagijẹ ti gbogbo awọn araadugbo maa n pe e, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lọwọ tẹ ẹ lori ẹsun ole jija.

ALAROYE gbọ pe o ti pẹ ti ẹran-agbo (ram) awọn eeyan agbegbe Ọlẹyọ, niluu Oṣogbo, ti maa n poora, ti wọn ko si fura si ẹnikẹni titi digba ti aṣiri fi tu bayii.

Alakooso ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Kọmreedi Amitolu Shittu, ṣalaye pe inu ile akọku kan, nibi ti Owolabi maa n ko awọn ẹran-agbo yii si ti wọn ba ti ji wọn lọwọ ti tẹ ẹ.

Amitolu ṣalaye pe ki i ṣe Owolabi nikan lo n huwa ibi yii, oun ati ẹgbọn rẹ kan to ti sa lọ bayii ni, laipẹ ni ọwọ yoo si tẹ oun naa.

O ni ẹran-agbo meji lawọn Amọtẹkun ba ninu ile akọku naa, to si jẹ pe ṣe ni Alfa ji wọn, eleyii si wa lara ọkẹ aimọye aṣeyọri ti ikọ amọtẹkun ti ṣe lẹnu igba ti wọn ti ṣedasilẹ rẹ nipinlẹ Ọṣun.

O ni awọn ti fa afurasi naa le ọlọpaa lọwọ fun iwadii to peye, o si kilọ fun gbogbo awọn ọdaran lati takete sipinlẹ Ọṣun nitori ikoko ko ni i gba ṣọṣọ ko tun gba ẹyin fun gbogbo wọn.

Leave a Reply