Jide Alabi
Lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ awọn ajinigbe mẹrin ti wọn wa si ipinlẹ Ekiti lati ipinlẹ Sokoto.
Ilu Ẹda Oniyọ, nijọba ibilẹ Ilejemeje, nipinlẹ Ekiti, lọwọ ti tẹ awọn Fulani darandaran naa ti wọn jẹwọ pe ajinigbe lawọn.
Nigba to n ṣafihan wọn fawọn akọroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, olori ẹṣọ Amọtẹkun, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, ṣalaye pe lasiko ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun n yide kiri ni wọn ri awọn eeyan naa, Abubakar Sule, Sheu Usman, Abubakar Babangida, Sheu Mamuda lori ọkada ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ.
Awọn ẹṣọ naa da wọn duro, wọn si beere ibi ti wọn ti n bọ ati ibi ti wọn n lọ. Wọn ni Ilọrin lawọn ti n gun ọkada bọ lẹyin ti wọn ja awọn silẹ lati Sokoto tawọn ti kuro ni nnkan bii ọjọ diẹ sẹyin.
Njẹ nibo ni wọn wa n lọ, wọn ni awọn n lọ si Akungba Akoko. Nigba ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun si beere ohun ti wọn n lọọ ṣe nibẹ, awọn eeyan naa ko ri alaye gidi kan ṣe fun wọn. Ṣugbọn wọn jẹwọ pe ajinigbe ni awọn.
Ọkan ninu ọkada ti wọn gun naa ko ni nọmba tabi iwe idanimọ kankan, bakan naa ni wọn ni ọkan ninu wọn kọ ọ lede Hausa sara ọkada rẹ pe ‘Duniyan Ba Hutu’ eyi to tumọ si ‘Ko si alaafia fun aye’. Yatọ si ọkada mẹrin ti wọn gun ọhun, awọn Amọtẹkun tun ri okun kan lọwọ wọn, eyi ti awọn eeyan naa jẹwọ pe awọn fi maa n so awọn eeyan ti awọn ba ji gbe.
Awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti ṣeleri lati fa wọn le ọlọpaa lọwọ fun iwadii to gbopọn.