Ọwọ EFCC ba awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹtala ni Lẹkki

Faith Adebọla, Eko

 

 

 

Agbegbe Lẹkki lawọn mẹtala to wa ninu fọto yii sa pamọ si ti wọn sọ jibiti lilu lori atẹ ayelujara di iṣẹ gidi, ṣugbọn awọn agbofinro ti wa wọn ri, wọn si ti fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn.

Orukọ wọn ni Adejumọbi Shonaike, Idris Ridwan, Afeez Kareem, David Adedire, Patrick Muodozie, Abidemi Smart, Foluwako David ati Adelẹyẹ Smart.

Awọn marun-un to ku ni Ọlawale Macaulay, Mayọwa Akinṣẹyẹ, Ọlabọde Thomas, Jimọh Ọlaitan ati Damilare Gabriel.

Ba a ṣe gbọ, ile kan to wa lẹyin l’Opopona Gabriel Ajawa, ni Lẹkki, nipinlẹ Eko, ni wọn mori mu si, ti wọn ti n ṣiṣẹ dudu ọwọ wọn.

Awọn aladuugbo kan ti wọn ti n fura si lilọ bibọ awọn gende mẹtala yii lo ta ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nni, EFCC, lolobo, lawọn agbofinro fi sabẹwo sọdọ awọn afurasi ọdaran naa, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee.

Ajọ EFCC sọ lori atẹ ayeluja tuita (twitter) wọn pe, afẹmọju lawọn ti lọọ ka awọn afurasi naa mọle, bi wọn si ṣe n ji lori bẹẹdi wọn, akolo awọn agbofinro ni won n bọ si.

Yatọ si awọn mẹtala yii, EFCC tun ko awọn kọmputa alagbeeleta ti wọn fi n lu jibiti, ati awọn nnkan eelo abanaṣiṣẹ, ọti lile, atawọn nnkan mi-in.

EFCC ni iwadiit tin lọ lọwọ lori wọn, atawọn ati irin-iṣẹ wọn lawọn maa wọ dewaju adajọ laipẹ, lati sọ bọrọ ṣe jẹ.

Leave a Reply