Ọwọ EFCC tẹ awọn afurasi ọmọ Yahoo mẹtalelogun n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Afi bii ẹni pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti nilẹ yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ṣọdun ikore awọn afurasi ọdaran pẹlu bo ṣe jẹ pe mẹtalelogun afurasi onijibiti lọwọ wọn tẹ lọjọ kan ṣoṣo.

Lọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun 2022 yii, ni wọn fi panpẹ ọba gbe awọn arufin naa laduugbo Apata, Jericho ati Ire-Akari Estate, n’Ibadan.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, niṣe lajọ EFCC lọọ ka awọn ọmọkunrin naa mọle, wọn si ṣa wọn bii igba ti ọmọde ba n ṣa eeṣan lẹgbẹẹgbẹ ogiri lẹyin ti awọn kan ti ta wọn lolobo pe awọn ọmọ Yahoo, iyẹn awọn to maa n lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara wa lawọn adugbo naa.

Bi wọn ṣe ko ẹrọ agbeletan (laptop) awọn afurasi naa ni wọn gba gbogbo ẹrọ ibanisọrọ ọwọ wọn. Ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla meje ọtọọtọ ni wọn ba ninu ọgba ile meje ninu awọn ọmọkunrin naa.

Mẹrindinlogun ninu awọn afurasi ọdaran yii la gbọ pe wọn lọwọ ninu jibiti ori ẹrọ ayelujara. Ẹrọ to n ṣayẹwo ila to wa lara awọn ọmọ ika ọwọ ọmọniyan lajọ naa lo lati da awọn mẹrẹẹrindinlogun mọ pẹlu ẹrọ agbeletan to jẹ ti kaluku wọn.

Orukọ awọn afurasi onijibiti ọhun ni Oluwọle Oduwanye Kelvin, Adams Ṣẹgun Ojo, Amuwo Oluwagbemi Oluwatobi, Theophilus Ademọla Akinyẹle, Mimiọla Ọlamide Victor, Ajayi Pẹlumi Pamilẹrin, Tolulọpẹ Adara Mati Timothy ati Bamgbose Temitayo Abiọdun.

Awọn yooku ni Ajibọla Timilẹhin Isreal, Ajibade Habeeb Ọlakunle, Tobilọba Isaiah Ṣeyi, Joseph Ọdunayọ Clement, Victor John Enya, Ọdẹbọde Temiloluwa Kẹhinde, Ọlaniyi Ajibọla Roqeeb, ati Olushọla Oyetunde Samuel.

Awọn mẹrẹẹrindinlogun taa darukọ wọn soke yii ni wọn ti fìdi ẹ mulẹ pe wọn lẹbọ lẹru nigba ti awọn meje isalẹ wọnyi jẹ awọn ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori wọn:

Ọladipọ Tunde Lawrence, Eludire Gbemileke Joseph, Gbenga Abiọna Wale, Ojuwaye Emeka Oluwaṣeun, Babatunde Kọlade Tunde, Abu Idris Ọlalekan ati Boye Timilẹhin Emmanuel.

Lopin gbogbo iwadii ajọ EFCC lawọn afurasi ọdaran wọnyi yoo foju ba ile-ẹjọ, iyẹn bi nnkan ko ba yipada lẹyin iwadii akọroyin wa.

Leave a Reply