Ọwọ EFCC tẹ awọn ọmọ ‘Yahoo’ mẹwaa l’Alagbado

Faith Adebọla, Eko

 

Awọn mẹwaa ni wọn ti wa lakata ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ wa, EFCC. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n lu awọn eeyan ni jibiti lori ẹrọ ayelajara, wọn n ṣe ‘Yahoo’.

Orukọ awọn tọwọ ba ọhun ni Rasheed Ogunlana, Jonathan Daniẹl Adebayọ, Prince Wilfred Efetobore, Waidi Lawal, Joseph Adeọṣun ati Rotimi Ṣowunmi.

Awọn mẹrin to ku ni Ọmọtayọ Oseni, Emmanuel Fakiyesi, Gbemileke Taiwo ati Ṣẹgun Ọladunni.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Ọgbẹni Wilson Uwajuren, ṣe fidi ẹ mulẹ fun ALAROYE, o ni olobo kan lo ta awọn nipa awọn afurasi ọdaran wọnyi. O lo ti ṣe diẹ tawọn ti n fimu finlẹ nipa wọn, igba ti iṣẹ iwadii tawọn ṣe too fi ibi ti wọn n gbe han lawọn ṣẹṣẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe wọn lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii.

Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ọkọ ayọkẹlẹ mẹta, kọmputa agbeletan, foonu oriṣiiriṣii, pasipọọtu ati iwe sọweedowo, titi kan ẹrọ igbalode ti wọn fi n ya fidio.

Ọgbẹni Wilson lawọn afurasi wọnyi ti ṣalaye ara wọn fawọn to n ṣiṣẹ iwadii lọdọ EFCC. O fi kun un pe iwadii naa lo maa pilẹ igbẹjọ wọn nigba ti wọn ba foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply