Ọwọ EFCC tẹ awọn to fẹẹ fowo ra ibo ‘Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti ṣafihan aọn kan tọwọ tẹ pe wọn fẹẹ fun aọn eeyan lowo lati ra ibo wọn.
Owo tuulu tuulu ni wọn ba lọwọ awọn eeyan naa ni ibudo idibo gẹgẹ bi ileeṣẹ tẹlifiṣan Channel ṣe sọ. Oju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa mu wọn, ti wọn si ko wọn lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Oke Ori Omi, nibi ti wọn ti ṣafihan wọn fawọn araalu.
Bakan naa ni awọn agbofinro gba owo nla lọwọ awọn kan ti wọn n gbiyanju lati pin owo naa fun awọn to fẹẹ dibo ni Wọọdu kẹwa, nijọba ibilẹ Ikẹrẹ Ekiti. Fun ọpọlọpọ iṣẹju ni ariyanjiyan fi waye laarin awọn agbofinro atawọn eeyan ọhun, eyi to da eto idibo ibẹ duro titi ti wọn fi ri ọrọ naa yanju.
Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), tun tẹ awọn eeyan kan ti wọn n fun awọn oludibo lowo.
Ninu fidio kan to n ja ran-in lori ẹrọ ayelujara ni wọn ti ṣafihan aọn ti wọn mu naa ati ọpọlọpọ owo ti wọn ba lọwọ wọn.
A gbọ pe ileewe girama, Ọlaoluwa Grammar School, to wa loju ọna Ilawẹ Ekiti, niluu Ado Ekiti, lawọn EFCC ko wọn lọ.

Leave a Reply