Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ Ṣeun to ta ọmọ oojọ to bi lẹgbẹrun marun-un fun wolii l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayefi nla lo jẹ loju awọn eeyan to wa nibi tawọn ẹsọ Amọtẹkun ti n fọrọ wa obinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Ṣeun Ọladayọ, lẹnu wo lori bo ṣe fẹẹ lu ọmọ oojọ to bi ninu ara rẹ ta ni gbanjo niluu Ondo.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe Ṣeun ti bimọ meji tẹlẹ ko too tun bi omiiran to jẹ ẹkẹta lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

Funra rẹ lo da ọmọ tuntun naa bi sinu ile baba iya rẹ to wa laduugbo Abẹjoye, lagbegbe Odojọmu, niluu Ondo, lai fu ẹnikẹni lara pe oun ti bimọ.

Bo ṣe bimọ tan lo sare pe ẹgbọn rẹ kan to n jẹ Yinka sori aago, to si ni ko tete ba oun wa ẹni ti yoo ra ọmọ tuntun jojolo ọhun ki ọrun oun le fuyẹ diẹ.

Ẹgbọn rẹ to ransẹ pe naa ko si fi akoko ṣofo to fi lọọ ba wolii kan pe ko tete wa owo jade, o ni oun lọmọ toun fẹẹ ta fun un.

Ninu alaye ti wolii ọhun, Ọlawale, ṣe fun akọroyin ALAROYE, o ni oun ti mọ Yinka ṣaaju ọjọ tiṣẹlẹ yii waye.

O ni oun kọkọ fẹẹ kọ jalẹ lati ra iru ọja bẹẹ lọwọ awọn mejeeji, ṣugbọn oun gba lati ra a ki wọn ma lọọ pinnu ati ta a fun ẹlomi-in to le fẹẹ lo o fun iṣẹ ibi.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, lo ti bimọ, inu agbara ẹjẹ lo ṣi ba ọmọ tuntun ọhun ati olubi rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ sile wọn.

O ni ẹgbẹrun marun-un Naira loun ba wọn dunaa dura si, funra tẹgbon-taburo naa ni wọn si gbe ọmọ wọn sinu baagi gana mọs go kan, ti wọn ni ko maa gbe e lọ.

Ni kete to gbe ọmọ naa kuro lọdọ wọn lo sare pe ọkan ninu awọn ẹsọ Amọtẹkun pe ko tete maa bọ lati waa wo oun toju oun ri.

Oun ati oṣiṣẹ Amọtẹkun yii ni wọn jọ gbe ọmọ tuntun ọhun ati olubi rẹ lọ sile, nibi ti wọn ti kọkọ wẹ fun un, ti wọn si tun wọṣọ si i lọrun.

Lẹyin eyi ni wọn pe Alaaji Akewuṣọla Tajudeen to jẹ ọga awọn Amọtẹkun nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo lati fohun to ṣẹlẹ to o leti.

Ṣeun to jẹ iya ọmọ tuntun yii nikan ni wọn ri mu nigba ti wọn yoo fi pada debẹ, wọn ko ba Yinka ẹgbọn rẹ mọ.

Wọn mu iya ọlọmọ mẹta naa lọ si ọfiisi wọn lagbegbe Civic Centre, niluu Ondo, nibi ti wọn ti fọrọ wa a lẹnu wo ki wọn too fa a le awọn ọlọpaa Area Command lọwọ.

Ṣeun ni ki i ṣe pe oun fẹẹ ta ọmọ ti oun ṣẹṣẹ bi ọhun gẹgẹ bawọn eeyan ṣe ro. O ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Tọpẹ lo fun oun loyun, ati pe ọjọ to ti gbọ nipa oyun naa lo ti sa lọ, ti oun ko si tun laju ri i titi ti oun fi bimọ.

O ni ohun ti oun sọ fun Yinka ẹgbọn oun lori ago ni pe ko ba oun wa ẹni ti yoo ba oun tọju rẹ nitori iya to n jẹ oun.

O ni ẹgbẹrun marun-un Naira ti oun fẹẹ fun dokita kan to waa gbẹbi fun oun lo ṣokunfa ẹgbẹrun mẹwaa tí oun n beere fun lọwọ wolii to fẹẹ gbe ọmọ lọ.

ALAROYE gbọ pe Iya Ṣeun ati Yinka ti pada yọju si agọ ọlọpaa, nibi ti wọn mu iya ọmọ tuntun naa lọ, lati lọọ sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply