Ọwọ Amọtẹkun tẹ awọn gbaju-ẹ marun-un l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi onijibiti marun-un ti wọn n ṣọṣẹ lagbegbe Ọja ọba, niluu Akurẹ.

Meji ninu awọn ọdaran ọhun, Ojo Dausi ati Francis Okorocha, lọwọ kọkọ tẹ lẹyin ti wọn ji ọmọbinrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Ẹniọla Adedipẹ gbe lọ si ọfiisi wọn, nibi ti wọn ti fi oogun abẹnu gọngọ gba gbogbo owo to wa ninu asunwọn ile-ifowopamọ rẹ.

Ninu alaye ti obinrin naa ṣe fun akọroyin wa, o ni lẹyin tawọn afurasi ọhun fi nnkan gba oun nikun lẹẹmẹta loun bẹrẹ si i tẹle wọn, ti oun si n ṣe ohun kohun ti wọn ba ti ni ki oun ṣe.

Ile kan ti wọn pe lọfìisi ni wọn kọkọ mu un lọ, nibẹ lo ti sọ nọmba aṣiri kaadi ipọwo rẹ fun wọn, eyi to fun wọn lanfaani lati lọọ gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira jade ninu asunwọn banki rẹ.

O to bii wakati mẹfa daadaa to ti pada de ile rẹ ki iye rẹ too ṣi pada, kiakia lo lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ẹsọ Amọtẹkun leti, ti wọn si gbe igbesẹ ati fi pampẹ ofin gbe Ojo, Okorocha atawọn ẹgbẹ wọn mẹta mi-in.

Alakooso agba fun ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Adetunji Adelẹyẹ, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni o ti le lọdun marun-un tawọn afurasi tọwọ tẹ ọhun ti wa lẹnu iṣẹ jibiti lilu.

Ọpọlọpọ awọn eeyan agbegbe  Ọja Ọba, Old Garage, Aafin Deji ati Cathedral, niluu Akurẹ, lo ni wọn ti foju wina ọkan-o-ọkan ọṣẹ ti wọn n ṣe.

O ni awọn ṣi n tesiwaju ninu iwadii awọn lori awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn mararun-un.

 

Leave a Reply