Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ awọn ọkunrin meji ti wọn n ṣe ‘kinni’ funra wọn l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

 

 

Boroboro bii ajẹ to jẹ eepo ọbọ ni awọn ọkunrin meji kan n ka lẹyin tọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo tẹ wọn nibi ti wọn ti n ṣe ‘kinni’ fun ara wọn niluu Akurẹ lọsẹ to kọja.

Awọn mejeeji, Balogun Seyi, ẹni ogoji ọdun, ati Tosin Arifalo, ti ko ti i ju bii ọmọ ọdun mejidinlogun lọ lawọn ẹsọ ọhun ka mọ ibi ti wọn ti n bara wọn lo pọ lagbegbe Kajọla, Ijọka, l’Akurẹ.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ọmọ bibi ilu Isua Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Ila-Oorun Akoko, ni Balogun, nigba ti Tosin jẹ ọmọ ilu Akurẹ ni tirẹ, wọn ni o ti to oṣu diẹ sẹyin ti wọn ti n bara wọn lo pọ, ṣugbọn ti ko sẹni to tete fura si wọn.

Nigba ti kinni ọhun si wọ Balogun lara tan, ṣe lo tun lọọ wa ẹlomi-in mọra tawọn mejeeji si jọ n kona fun ọmọ ọlọmọ.

Nigba to n ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn, Balogun ni jẹẹjẹ oun loun jokoo nigba ti Tosin waa dẹnu ifẹ kọ oun, to si ni kawọn mejeeji maa fẹra.

O ni oun kọkọ kọ jalẹ fun un, ṣugbọn nigba ti wahala rẹ fẹẹ pọ ju, to si tun n dunkooko mọ ẹmi oun loun gba fun un.

Nigba ti Tosin naa n sọ tẹnu rẹ, o ni Balogun gan-an lẹni to fipa mu oun wọnu ẹgbẹ kì ọkunrin maa ṣe ‘kinni’ funra wọn.

O ni lẹyin ti awọn ti ṣe e bii ẹẹmẹta ninu ile rẹ n’Ijọka, lo tun lọọ mu ọrẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Olojijo wa, tiyẹn naa si tun ba oun lo pọ lọpọlọpọ ìgbà.

Awọn ẹsọ Amọtẹkun ti fa awọn mejeeji le ajọ sifu difẹnsi lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

Leave a Reply

//outrotomr.com/4/4998019
%d bloggers like this: