Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun tẹ Sunday to n ja sọọsi lole l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti tẹ Akinọla Sunday Francis ti wọn lo n ja awọn sọọsi lole l’Akurẹ.

Ni ibamu pẹlu alaye ti Wolii Gbenga Filani to jẹ ọkan ninu awọn oludasilẹ awọn sọọsi ti wọn ni afurasi ọhun wọ inu rẹ laipẹ yii ṣe fun wa, o ni lati bii osu diẹ sẹyin lawọn ole kan ti n fọ awọn ijọ CAC, Sẹlẹ ati Kerubu to wa lagbegbe Ilẹkùn, loju ọna Ọda, niluu Akurẹ.

O ni ọpọlọpọ sọọsi ni wọn ti fọ, tí wọn sì ń ko awọn aago igbala ti wọn ba ti ba nibẹ lọ lai mọ ohun ti wọn fi n ṣe.

Wolii yii ni ṣọọsi oun ni wọn kọkọ fọ lọsẹ to kọja, ṣugbọn ole ọhun ko ti i raaye ko awọn aago ti awọn n lu to fi sa lọ nigba to ṣakiyesi pe awọn eeyan fẹẹ kofiri oun.

O ni ko ju bii ọjọ diẹ lọ lẹyin naa tọwọ fi tẹ afurasi ọhun lasiko to tun lọọ fọ sọọsi mi-in lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

O ni ṣe lo ba gbogbo ilẹkun atawọn gilaasi oju fereṣe ṣọọṣi naa jẹ lasiko to n gbiyanju ati fipa wọle.

Ninu ọrọ ti ọmọkunrin naa sọ fun wa nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo lo ti ṣẹ kanlẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni oun ki i ṣe ole rara, bẹẹ si ni oun ko ba wọn jale ri lati igba ti wọn ti bí oun saye.

O jẹwọ pe loootọ loun wọ inu ṣọọṣi ti wọn ka oun mọ, ṣugbọn ki i ṣe pe oun lọ sibẹ lati jale gẹgẹ bii ẹsun ti wọn fi kan oun.

Ọpọ igba lo ni oun ti waa ba wọn jọsin ninu ṣọọṣi ọhun, ti ko si sẹni to le sọ pe oun ka oun mọ ibi ole jija rí.

O ni ko ye oun iru ẹmi to ba le oun lojiji lọjọ naa to fi di pe oun fi aago igbala tọwọ oun tẹ fọ awọn ilẹkun ṣọọṣi ti wọn ka oun mọ yii.

Gẹgẹ bi iwadii ta a ṣe, ọmọ bibi ilu Igbimọ-Ekiti ni wọn pe ọmọkunrin naa, Fasiti Adekunle Ajasin to wa l’Akungba Akoko ni wọn lo ti n kawe lọwọ.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti fa afurasi ọhun le awọn ẹsọ Amọtẹkun ilu Akurẹ lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

Leave a Reply