Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ajọ fijilante ipinlẹ Ekiti, ti kede pe ọwọ ti tẹ eeyan mẹta ti wọn maa fọ ile ile onile, ti wọn yoo si tun yọ batiri ọkọ nibi ti wọn ba gbe e si.
Awọn ọdaran mẹta naa ti wọn jọ n ṣiṣe ole jija ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Sunday, ẹni ogójì ọdun, to jẹ olori wọn. Gbogbo awọn eeyan naa ni wọn ti wa latimọle ọlọpaa ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ado-Ekiti.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmandati awọn fijilante nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Akin Ọlọunloni, ni ọwọ tẹ awọn ọdaran naa pẹlu ifọwọsọwọpọ awọn araalu. O ṣalaye pe ni kete ti ọwọ tẹ wọn ni oriṣiiriṣii awọn ẹsun miiran tun n jade latọdọ awọn araalu pe awọn ọdaran meji naa gbowọ ninu ole jija, ti wọn si ti n da awọn araalu laamụ lati akoko diẹ sẹyìn.
O fi kun un pe ni kete ti wọn pari iwadii lati ọdọ awọn fijilante ni awọn jọwọ awọn ọdaran naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, ati lati foju awọn ọdaran naa wina ofin.
O ṣalaye pe awọn ọmọ ogun oun ti bẹrẹ igbesẹ lati mu awọn yooku awọn ọdaran naa ti wọn sa lọ lakooko ti wọn lọ si ibuba wọn.