Ọwọ fijilante tẹ Sanni to pa ọmọ aburo baba rẹ niluu Irawọ

Olu-Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun

Akitiyan awọn ẹṣọ alaabo Fijilante lati jẹ kijọba ibilẹ Atisbo wa lalaafia ti n seso rere pẹlu bọwọ wọn ṣe tẹ Abubakar Sanni, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) to pa ọmọ aburo baba rẹ lati le gbẹsan iwa aburu to ni baba oloogbe naa hu si baba oun.

Ọjọruu, Wẹside, ọsẹ to kọja yii ni Kọmanda Fijilante agbegbe naa, Oloye Ademọla Ọlawoore, ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa lọfiisi wọn to wa niluu Tede ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ naa.

Ọlawoore ni ninu oṣu keje, ọdun yii, lawọn mọlẹbi oloogbe naa fi to wọn leti pe ọmọ Fulani kan, Yakubu Sanni, dawati lẹyin ti wọn da maaluu lọ si agbegbe Irawọ, nijọba ibilẹ Atisbo, pẹlu erongba pe boya o ti bọ sọwọ awọn ajinigbe lakooko to n da maaluu kiri.

O ni latigba naa lawọn Fijilante yii ti n fimu finlẹ kiri.

Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, lọwọ pada tẹ Abubakar lẹyin ọpọlọpọ akitiyan wọn.

Lakooko to n ka boroboro lọfiisi wọn ni Abubakar ti jẹwọ pe awọn meta lawọn lọwọ ninu iṣekupani ọjọ naa, toun si mọ ibuba tawọn yooku wa, ki ọwo awọn agbofinro le tẹ wọn. Gẹgẹ bo ṣe sọ, Abule Oniyawo-mẹta, ti ko fi bẹẹ jinna siluu Irawọ, lo lawọn da maaluu lọ lọjọ naa, tawọn si gbimọ-pọ tan Yakubu lọ.

O ni lẹyin tawọn fun un lọrun titi tẹmii fi bọ lara ọmọọdun mẹsan-an ọhun lawọn gbẹ saree ṣukẹsukẹ kan, tawọn si sinku rẹ si.

Agbari oku to ti jẹra pẹlu ẹya-ara ati aṣọ oloogbe naa lawọn agbofinro hu jade.

Afurasi ọdaran yii ṣalaye pe nnkan to jẹ koun gbe igbesẹ naa ni lati fi gbẹsan owo maaluu ti baba oloogbe naa ra lọwọ baba oun, ṣugbọn ti ko sanwo rẹ tan to fi ku.

Oloye Ọlawoore tawọn ba ti pari iwadii lawọn yoo taari wọn sagọọ ọlọpaa.

Leave a Reply