Owo ‘gba, ma binu’, gbọdọ wa fawọn ti SARS pa nipakupa-Awọn gomina

Ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria ti sọ pe ki i ṣe iru asiko yii lo yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa sare da ẹṣọ agbofinro mi-in ti wọn pe ni SWAT silẹ.
Nibi ipade tawọn gomina yii ṣe niluu Abuja ni wọn ti sọrọ yii. Bakan naa ni wọn fi kun un pe pẹlu idasilẹ ẹṣọ agbofinro tuntun SWAT yii, ohun tawọn araalu yoo maa sọ ni pe awọn SARS naa ni wọn ṣì wa lẹnu iṣẹ, ati pe niṣe ní wọn kan sọ wọn lorukọ mi-in.
Gomina Kayọde Fayẹmi ti i ṣe alaga awọn gomina sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ ṣètò bi yoo ṣe máa ṣepade pẹlu awọn eeyan ti ọrọ kan laarin ilu, bẹẹ ni atunṣe pẹlu agbeyẹwo awọn ohun to ni i ṣe pẹlu awọn ọlọpaa ṣe pataki lati ṣe koriya fun wọn. O ni bi eto ba ṣe n waye lori bi ẹkunwo yoo ṣe ba owo oṣu awọn ọlọpaa, bẹẹ naa ni wọn gbọdọ maa ṣeto idanilẹkọọ fun wọn lọpọ igba.
Siwaju si i, awọn gomina ọhun ti sọ pe awọn ti ṣetan bayii pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣeto igbimọ ti yoo ṣakojọpọ gbogbo orukọ awọn eeyan ti ọlọpaa pa nipakupa atawọn mi in ti wọn fiya jẹ lọna aitọ kaakiri orilẹ-ede yii lati ṣeto gba ma binu fun wọn.
Awọn gomina yii ti waa rọ ọga ọlọpaa ko gbiyanju lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn gomina atawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ, ki ajọṣepọ to dara le wa laarin ọlọpaa ati araalu.
Wọn lọ ṣe pataki kí ileeṣẹ ọlọpaa ṣawari awọn ẹṣọ agbofinro to fiya jẹ araalu lọna aitọ, kiru ẹni bẹẹ si foju wina ofin pẹlu ijiya to yẹ.

Leave a Reply