Owo iṣẹ ti Rasheed ṣe lo fẹẹ lọọ gba tawọn kọsitọọmu fi yinbọn pa a n’Igbo-Ọra

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bi ko ṣe sẹni to n ro wiwo ro igi tutu ninu oko ni ko sẹnikan to ro iku ro ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan torukọ ẹ n jẹ Rasheed Kọlawọle. Idi ni pe ọmọde to n ṣiṣẹ ẹ jẹẹjẹ, to si n gbọ bukaata idile oniyawo meji pẹlu ọmọ marun-un to bi ni.

Afi bo ṣe pade iku ojiji lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, loju ọna to lọ si Igbo-Ọra, nipinlẹ Ogun, wọn si lawọn kọstọọmu lo yinbọn pa a.

AKEDE AGBAYE gbọ pe dẹrẹba ni Rasheed, awọn alajapa lo maa n fi mọto rẹ gbe. Owo iṣẹ to ṣe naa lo fẹẹ lọọ gba lọjọ naa pẹlu aburo ẹ tiyẹn n jẹ Mohammed Ramon.

Ori ọkada ni wọn jọ wa ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa ti wọn fi pade ọlọkada kan lagbegbe Iyana Ọgangan, bi wọn ṣe kọja lara ọlọkada naa ni wọn tun ri mọto Camry kan tiyẹn naa n bọ.

Lẹyin ti awọn ọkada ati mọto yii kọja tan ni wọn ri mọto kan ti wọn kọ orukọ ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa si, awọn oṣiṣẹ to wọṣọ kọsitọọmu lo si wa ninu mọto naa gẹgẹ bi Muhammed ṣe wi.

Aburo oloogbe ṣalaye pe bawọn ṣe de Yewa Central College, nitosi Rounder, ni awọn aṣọbode naa da awọn duro, Rasheed si sọkalẹ lori ọkada pẹlu ibẹru, bi aṣọbode kan ṣe fabọn yọ niyẹn, to si yin in.

Bo ṣe yinbọn naa lawọn yooku ẹ sare tẹle Rasheed, ti wọn n le e lọ, bẹẹ ni wọn mu Muhammed naa, ti wọn bẹrẹ si i lu u.

Ọmọkunrin yii sọ pe awọn aṣọbode yii gbe oun sinu mọto wọn, bẹẹ oun ko jale, bẹẹ loun ati ẹgbọn oun ko ba wọn da nnkan kan pọ ri.

O nigba to pẹ ti wọn ti n lu oun ni ọkan ninu wọn sọ pe ẹni yii ko mọ nnkan kan, ki i ṣe awọn meji tawọn pade yii lawọn n wa, sibẹ, awọn to le Rasheed lọ ko pada, bẹẹ ni iro ibọn ko yee dun.

Nigba to ya ni wọn yọnda Muhammed, ọmọkunrin naa si bẹrẹ si i wa ẹgbọn ẹ lagbegbe naa, ṣugbọn ko ri i. Ọjọ keji lo fi to awọn ọlọpaa leti, ni wọn ba bẹrẹ si i wa Rasheed kiri.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ni wọn too ri oku ẹ ninu koto to da oju de si.

Ile igbooku-si jẹnẹra to wa n’Ijaye, l’Abẹokuta, ni wọn kọkọ gbe oku naa lọ lati yọ ọta ibọn to wa lara ẹ, ko too di pe wọn sin in.

Ẹgbẹrun lọna ogoje naira (140,000) lowo ti wọn ba lapo oloogbe Rasheed Kọlawọle gẹgẹ ba a ṣe gbọ, aburo rẹ yii naa la si gbọ pe wọn ko o fun.

Titi ta a fi pari akọjọpọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ awọn kọstọọmu ti wọn ni wọn ṣiṣẹ yii, bẹẹ ni ọwọ ko ti i ba ẹnikankan ninu wọn.

Leave a Reply