Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Araba awo ti ilẹ Oṣogbo, Oloye Ifayẹni Ẹlẹbuibọn ti sọ pe ti iwa ifipabanilopọ to ti di tọrọ-fọn-kale lorileede Naijiria bayii yoo ba di afisẹyin teegun n fiṣọ, ojuṣe ijọba lo pọ ju ninu ẹ.
Lasiko ti baba n ba ALAROYE sọrọ lori foonu lori ọna ti opin fi le de ba iwa buburu ọhun lo sọ pe ohun itiju ti ko yẹ ka maa gbọ lawujọ awọn eeyan ni iwa ifipabanilopọ jẹ.
Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe ki i ṣe oju lasan ni awọn ti wọn n huwa naa fi n hu u, wọn maa n wa labẹ idari oogun-oloro ni.
O ni tijọba ba le gbe igbesẹ akin lati fopin si kiko awọn oogun oloro bii tramadol wọ orileede Naijiria, iwa ibi naa yoo dinku jọjọ.
“Ijọba gbọdọ fofin de kiko awọn oogun-oloro ti awọn eeyan yẹn maa n mu wọ orileede yii. Ẹ ri i pe oniruuru ọna lawọn eeyan wa nibi n gba ṣe ẹda awọn oogun amarale yẹn naa bayii.
“Ko si eyi ti wọn ṣe labẹle nibi ti wọn ko ni i fi diẹ lara awọn oogun-oloro to n wa lati okeere yẹn si i, ti wọn ba si ti mu un tan, obinrin kobinrin ti wọn ba ti ri nitosi ni wọn aa ki mọlẹ.
“Ọrọ ifẹ ki i ṣe tulaasi, ọkẹ aimọye obinrin lo wa laye, ṣugbọn iṣẹkiṣẹ ni awọn oti-lile ti wọn n mu yẹn n ṣe lagọọ ara wọn, ohun lo si maa n jẹ ki wọn ṣiwa-hu, afi kijọba fofin de kiko awọn ọti ọhun wọle”.