Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Sẹnetọ Kashim Shettima, ti fawọn ọmọ Naijiria lọkan balẹ pe gbogbo igbesẹ Tinubu ati ijọba rẹ, ki i ṣe lati ni awọn eeyan lara, bi ko ṣe lati yi igbe aye orilẹ-ede Naijiria pada si ti daadaa.
Shettima sọrọ yii nile ijọba, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to de si ile ijọba, ni nnkan bii aago kan ọsan ku iṣẹju mọkanlelogun. O ni gbogbo ileri ti Tinubu ṣe lasiko ti wọn n bura fun un gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lọjọ Aje, ni yoo mu ṣẹ, titi kan ọrọ owo iranwọ epo rọbi.
O tẹsiwaju pe ko si bawọn arijẹnimọdaru ẹda ti wọn n kowo iranwọ ọhun da sapo ara wọn ko ṣe ni i fọn ẹnu firi pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ yọ owo naa kuro. Ati pe ipinnu awọn lori yiyọwo iranwọ ko yipada, nitori akoba nla to jẹ forilẹ-ede yii.
O ni, “Aarẹ ti mẹnuba ọrọ owo iranwọ ori epo nibi eto iburawọle rẹ, ootọ ọrọ to wa nibẹ ni pe ọkan ni yoo ṣẹlẹ, ninu ka fopin si ọrọ epo rọbi tabi ko sọ orilẹ-ede yii di ero ẹyin patapata.
Lọdun 2022, biliọnu mẹwaa dọla nijọba ana na lori iranwọ epo nikan. Nnkan to daju ni pe awọn ti wọn n ri jẹ ninu owo ti wọn fẹẹ yọ yii yoo gbogun, ṣugbọn ipinnu ta a ti ṣe ni, o gbọdọ lọ ba a ti ṣe ṣeto ẹ. Ẹ lọọ fọkan balẹ, nitori o-wi-bẹẹ ṣe bẹẹ ni Aarẹ wa”.
Shettima ṣalaye siwaju pe nnkan teeyan ko gbọdọ fi silẹ ko pẹ ni ọrọ iranwọ epo, ko too buru ju bo ṣe wa lọ, ati pe laipẹ yii lawọn eeyan yoo ri aniyan daadaa ti Aarẹ ni fun ilẹ Naijiria.