Owo itusilẹ awọn ti wọn ji gbe lawọn mẹta yii fẹẹ gba tọwọ fi ba wọn 

Adefunkẹ Adébiyi, Abẹokuta

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ni awọn mẹta yii, Abubakar Sọdiq, Ibrahim Kuaki ati Muhammadu Dio, bọ sọwọ ọlọpaa lasiko ti wọn fẹẹ gbowo itusilẹ lọwọ ẹbi awọn ti wọn ji gbe l’Abule Ọba Alamala, loju ọna Ayetoro, ipinlẹ Ogun.

Teṣan ọlọpaa Ilupeju ni Olobo ta, pe awọn ajinigbe ti ji awọn ọkunrin meji kan ti wọn lọọ ṣiṣẹ l’Abule Ọba Alamala gbe.

Eyi lo mu DPO teṣan naa ko awọn ikọ rẹ jọ pẹlu awọn ṣọja ati fijilante So-Safe, wọn wọgbo lọ lati wa awọn ajinigbe naa ri, ki wọn si gba awọn ti wọn ji gbe pada lalaafia.

Nibi ti wọn ti n fọgbo kiri ni wọn ti gbọ pe awọn ajinigbe ọhun ti kan si mọ̀lẹ́bí awọn ti wọn ji gbe, wọn ti sọ iye ti wọn yoo gbe wa gẹgẹ bi owo ìtúsílẹ̀ ati ibi ti wọn yoo gbe e wa fún wọn.

Kia lawọn agbofinro gba ibẹ lọ, wọn fara pamọ, wọn n reti awọn ti yoo jade waa gbe owo ọhun.

Ko pẹ sigba naa lawọn ẹruuku jade lati inu igbo, wọn fẹẹ gbe owo itusilẹ.

Bawọn agbofinro ṣe ri wọn ni wọn jọ ṣina ibọn bolẹ funra wọn, nigba tawọn ajinigbe ri i pe ọwọ awọn ọlọpaa, ṣọja ati fijiante yii ju tawọn lọ ni wọn bẹrẹ si i sa lọ, nigba naa lọwọ ba aawọn mẹta yii, awọn yooku wọn si gbe ọta ibọn sa lọ gẹ́gẹ́ bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

Awọn agbofinro ri awọn ti wọn ji gbe naa gba padà, wọn si ti pada sile wọn.

Awọn tọwọ ba yii ti wa lẹka to n gbọ ẹjọ ijinigbe, bẹẹ lawọn ọlọpaa n wa awọn yooku wọn ti wọn ni wọn gbe ọta ibọn sa lọ.

Bi ẹnikẹni ba kofiri ẹnikan to n gbe ọgbẹ ibọn kiri, paapaa awọn ileewosan, wọn ni ki wọn fi to ọlọpaa leti.

Leave a Reply