Owo Naira tuntun: Awọn aṣofin fẹẹ fọlọpaa gbe Emefiele

Monisọla Saka

Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin ilẹ wa, Fẹmi Gbajabiamila, ti ṣeleri pe oun yoo pa a laṣẹ fun Olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, lati waa kawọ pọnyin rojọ niwaju ile, gẹgẹ bi abala kọkandinlaaadọrun-un iwe ofin ilẹ wa ṣe fun awọn aṣofin laṣẹ lati fi panpẹ ọba gbe ẹnikẹni yoowu ti wọn ba ranṣẹ pe ti ko jẹ ipe wọn.

Emefiele lawọn aṣofin yii n binu si, ti wọn si tun fẹsun kan an lori bo ṣe kọ lati fi kun ọgọrun-un ọjọ to kede pe wọn yoo fi ko awọn owo atijọ ti wọn ṣe atuntẹ rẹ, (ọgọrun-un Naira, Igba Naira ati Ẹẹdẹgbẹta Naira), kuro nilẹ, eyi ti yoo pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ti wọn ko si tun kowo tuntun ọhun jade fawọn eeyan lati maa na.

O tẹsiwaju pe, olori banki apapọ (CBN), kọ lati sun ọjọ naa siwaju, lai wo ti awọn eeyan ti wọn n gbe ni igberiko, ti banki kankan ko sun mọ wọn, ki wọn baa le lanfaani lati ko awọn owo atijọ yii lọ sile ifowopamọ, ko ma baa di gbese si wọn lọrun. Bakan naa lo ni awọn ẹrọ to n pọ owo atawọn oṣiṣẹ inu banki ko tori ẹ da owo atijọ naa duro ni sisan, wọn ko si ko tuntun fawọn eeyan lati paarọ tọwọ wọn.

Lasiko ijokoo awọn aṣofin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni yii, ni wọn ti gbe awọn igbimọ kan dide laarin awọn aṣofin lati ba banki apapọ ilẹ wa atawọn adari ile ifowopamọ nilẹ yii sọrọ lori ọwọngogo owo Naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ ati ọrọ okoowo ori ẹrọ ayelujara ti ko nilo ka maa gbe owo beba kiri (cashless policy) ti wọn n fọnrere rẹ. Wọn ni ki banki to ga ju lọ ọhun sun ọjọ ti wọn kede pe awọn yoo ko owo atijọ kuro nilẹ siwaju si i fun oṣu mẹfa, kawọn araalu le ribi palẹmọ daadaa.

Bi ko ṣe si eyikeyii ninu olori banki apapọ ati aṣoju rẹ kankan to jẹ ipe awọn aṣofin nibi ipade ti wọn fi si aago mẹta Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lo mu ki wọn pe wọn si ipade mi-in lọjọ keji ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii kan naa. Wọn ni ṣaaju akoko yii ni wọn ti kọkọ ranṣẹ pe Emefiele, ṣugbọn to sọ pe ara oun ko ya, oun si ti lọ si oke okun lati ṣe itọju ara oun, ṣugbọn to kọ ti ko yọju lẹyin to pada de si Naijiria.

Ninu lẹta ti ti igbakeji olori banki apapọ buwọ lu, eyi ti Gbajabiamila ka seti gbogbo ile l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni wọn ti ni Emefiele ko ni i le yọju, nitori pe o wa lara awọn eeyan ti Aarẹ Buhari yan lati ṣoju oun niluu Dakar, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede Senegal.

Nigba to n sọ si ọrọ to wa ninu lẹta ọhun, Gbajabiamila ni bo tilẹ jẹ pe eeyan oun, ọrẹ oun daadaa, ni Emefiele, sibẹ oun pẹlu awọn ọmọ ile to ku ko ni i ṣalai gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa.

O ni kikọ ti olori banki apapọ ilẹ wa kọ lati yọju sibi ipade tawọn pe e si, tabi ko tilẹ ran eeyan kan wa lati waa ṣoju fun un ko ni i jẹ itẹwọgba lọdọ awọn rara, ati pe bo fẹ bo kọ, o gbọdọ yọju sibi tawọn pe e si kilẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to ṣu.

O tẹsiwaju pe ti Emefiele ba fi waa kọ lati yọju lati jiroro lori ofin tuntun to gbe jade, ofin to n ko inira ati idaamu ba awọn araalu, a jẹ pe oun yoo pada gbe igbesẹ nibaamu pẹlu ofin ilẹ wa, lati paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata nilẹ yii, Usman Alkali, pe ki wọn fi panpẹ ọba gbe e, ko si yọju sibi ipade naa ni kiakia.

Leave a Reply