Ọrẹoluwa Adedeji
Kilogiraamu oogun oloro ti wọn n pe ni kokeeni ti idi rẹ jẹ marunlelọgọjọ (165) ni awọn meji kan, Elvis Uche Iro ati Uwaezuoke Ikenna Christian, ya bii igbẹ lakata ajọ to n gbogun ti oogun oloro niluu Abuja nigba tọwọ tẹ wọn.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ naa, Fẹmi Babafẹmi, ṣe ṣalaye, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe lasiko ti wọn fura si awọn eeyan naa ti wọn ko wọn jọ sibi kan ti wọn ti n ṣayẹwo wọn ni wọn ni awọn eeyan naa ya kokeeni ọhun.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn mu Elvis, to jẹ baba ọlọmọ mẹrin, to wa lati ilu kan ti wọn n pe ni Abiriba, nijọba ibilẹ Ohafia, nipinlẹ Abia, nigba to wọ ọkọ ofurufu Ethiopia to n bọ lati Addis-Ababa.
Idi kokeeni bii marundinlaaadọrin ti kilogiraamu rẹ jẹ (1.376kg) lo ya mọ igbẹ.
Nigba ti wọn n wadii ọrọ lẹnu rẹ, o ṣalaye pe iṣẹ awọn ti wọn maa n baayan ṣe ẹṣọ si inu ile loun n ṣe tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti ọja naa ko lọ deede loun pinnu lati bẹrẹ si i ta kọfi, ki oun si ṣetọju awọn mọlẹbi oun, ki oun si tun le ri owo ra ọja si ṣọọbu oun toun ṣẹṣẹ gba, loun fi lọọ gbe oogun oloro yii.
O ni ka ni oun ṣe aṣeyọri ninu gbigbe oogun oloro naa de Abuja ni, ẹgbẹrun kan dọla loun iba gba lori rẹ.
Bakan naa ni wọn mu Uwaezuoke Ikenna Christian, to wa lati Odoto, nijọba ibilẹ Idemilli, nipinlẹ Anambra. Awọn aṣọ ọmọde lo ni oun n ta ki oun too bẹrẹ si i gbe oogun oloro.
Idi ọgọrun-un kokeeni loun naa ya mọgbẹẹ, ti iwọn kilogiraamu rẹ si jẹ (2.243kg). O ni lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii, loun lọ si Addis-Ababa lati lọọ ra oogun oloro naa ni ẹgbẹrun mẹwaa dọla ($10,000), o ni nigba toun n pada bọ lọjọ kọkandinlogun, oṣu naa, ni wọn mu oun.
O ṣalaye pe niṣe ni oun ta ilẹ ti oun ni si abule awọn, ti oun si tun yawo lọwọ awọn ọrẹ oun lati fi ra oogun oloro naa. O ni ohun to gbe oun de idi oogun oloro ni bi ẹnikan to n gbe orileede China ṣe lu oun ni jibiti ẹgbẹrun mẹẹẹdogun dọla (15,000).