Owo lolukọ Fasiti Ilọrin yii fẹẹ lọọ gba ni banki to fi dawati ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Olukọ ile ẹkọ giga Fasiti ilu Ilọrin, Ọjọgbọn Raphael Babatunde Adeniyi, ẹni ọdun mẹtalelọgọta, lo ti dawati lẹyin to dagbere pe oun fẹẹ lọọ gba owo ni banki to wa ni agbegbe Tankẹ, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe Adeniyi jẹ olukọ ni ẹka eto isiro (Mathematics) ni fasiti naa, to si n gbe ni agbegbe Tankẹ.

Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹfa, ọdun yìí, ni Ọjọgbọn naa kuro nile pẹlu ero ati lọọ gbowo ni banki GT ti ko jinna pupọ si ibi to n gbe. Ṣugbọn lati ọjọ naa, alọ ni awọn ẹbi rẹ ri, wọn ko ri abọ rẹ.

Awọn mọlẹbi ti waa kegbajare pe ki ẹnikẹni to ba kofiri Ọjọgbọn Adeniyi pe nọmba yii : 08065250697 tabi ko kan si agọ ọlọpaa to ba sun mọ irufẹ ẹni bẹẹ ju lọ.

 

Leave a Reply