Ọwọ NSCDC tẹ afurasi meji fẹsun jiji ẹrọ kọmputa gbe n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

 

 

Afurasi meji; Ọlanrewaju Mayọwa, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Oyindamọla Yusuf, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ni wọn wa lakolo ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, niluu Ilọrin bayii, fẹsun jiji ẹrọ kọmputa alagbeeka.

Atẹjade lati ọdọ Alukoro ileeṣẹ NSCDC nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ayẹni Ọlasunkanmi, ṣalaye pe ẹnikan lo fi to ileeṣẹ naa leti lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun yii, pe awọn ole ji ẹrọ kọmputa mẹẹẹdogun gbe ninu ṣọọbu awọn to wa ni Taiwo Isalẹ, niluu Ilọrin.

Ayẹni ni pẹlu awọn ohun ti onitọhun sọ fawọn, awọn mejeeji yii gan-an lawọn fura si pe wọn ṣiṣẹ ibi naa.

O niwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa, lẹyin iwadii lawọn afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

Atẹjade ọhun ni Ọga agba ajọ NSCDC ni Kwara, Alhaji Makinde Ayinla, ṣekilọ fun araalu lati ṣọra fun ohun ti wọn ba n ra, paapaa awọn nnkan atọwọdọwọ ti wọn ko mọ ibi to ti ṣẹ wa.

Leave a Reply