Ọwọ ọlọpaa atawọn ọlọdẹ tẹ ikọ adigunjale ti wọn jẹ obinrin l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ọdọbinrin mẹta ti wọn n digunjale niluu Oṣogbo ni wọn ti ko si ọwọ awọn ọlọpaa atawọn ọlọdẹ bayii.

A gbọ pe awọn adigunjale naa ti pitu ọwọ wọn ninu ile iya agba kan to ṣẹṣẹ ṣenawo lai si idiwọ lagbegbe Arẹsa, niluu Oṣogbo, ti wọn si ko owo nibẹ nidaaji ọjọ Aje, Mọnde.

Bi wọn ṣe kuro nibẹ ni wọn duro nibikan lati pin owo ti wọn ji ọhun, ni wọn ba tuka, ṣugbọn ọkan lara wọn to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla ko sọwọ awọn ọlọdẹ ni nnkan bii aago mẹrin idaji.

Bi ilẹ ṣe mọ ni awọn ọlọdẹ ranṣẹ si awọn ọlọpaa, bi wọn si ṣe de ibi ti wọn fi ọmọbinrin yii pamọ si, o jẹwọ, o si ṣeleri lati mu wọn debi ti awọn yooku rẹ wa.

Alaroye gbọ pe awọn ọlọdẹ atawọn ọlọpaa ni wọn tẹle e, ọwọ si tẹ ọkan lara wọn to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun ninu ile ọkọ rẹ lagbegbe Olugun, nigba ti wọn ri ekeji mu lagbegbe Ṣaṣa.

Alaga ẹgbẹ awọn ọlọdẹ nipinlẹ Ọṣun, Ahmed Nureen, sọ pe loootọ lawọn mu awọn ọmọbinrin mẹta ti wọn n digunjale l’Oṣogbo, amọ oun ko le sọ ẹkunrẹrẹ lori ẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe wọn ti fa awọn mẹtẹẹta le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iwa ṣiṣe ẹgbẹ okunkun lọwọ.

Leave a Reply