Faith Adebọla, Eko
Ahamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran mejidinlọgọta tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣẹṣẹ ba ti n gbatẹgun bayii. Iṣẹ janduku ati idaluru lawọn ni wọn n ṣe tọwọ fi ba wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Hakeem Odumosu, sọ f’ALAROYE pe lati bii ọjọ diẹ sẹyin lawọn ti n gburoo bi awọn ọmọ iṣọta naa ṣe n dun mọhuru mọhuru mọ awọn olugbe isalẹ Eko, ti wọn si n ko awọn eeyan lọkan soke latari oriṣiiriṣii iwa janduku ti wọn n hu. Eyi lo mu kawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fọn ka sagbegbe naa, ti wọn si finmu finlẹ titi ti wọn fi wadii ibuba awọn afurasi ọdaran wọnyi ati ibi ti wọn n gbe.
Lara ẹsun to ka si wọn lẹsẹ ni ole jija, fifọ ṣọọbu oniṣọọbu, jija baagi ati foonu awọn eeyan gba, ija igboro, biba dukia awọn eeyan jẹ, hihalẹ mọ awọn araalu, fifi ipa ba obinrin lo, atawọn iwakiwa bẹẹ lo kun ọwọ wọn. O lawọn mi-in tun maa n fipa gba owo lọwọ awọn onimọto ati ero ọkọ, wọn si maa n jale loju popo pẹlu.
Odumosu ni lẹyin tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti sami si awọn afurasi wọnyi, ti wọn ti mọ awọn abẹtẹ wọn, lawọn waa ṣeto ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa (Rapid Response Squard) RRS, atawọn ẹṣọ alaabo ilu nipinlẹ Eko (Lagos State Neighborhood Safety Corps), awọn fijilante naa tun dara-pọ mọ wọn, ni wọn fi le mu awọn ọmọ ganfe naa lẹẹkan naa, wọn si ṣiṣẹ naa doju ami. ACP Bọde Ọjajuni to jẹ Eria Kọmanda Area A lo ṣaaju wọn lọ.
Arugbo tọjọ ori wọn to ẹni aadọrin ọdun ni mẹrin ninu wọn, orukọ wọn ni: Sikiru Kareem, Kamal Ọlatoyinbo, Musa Alidu ati Sulaimọn Alaga, wọn lawọn eleyii lo n ṣe babaasalẹ fawọn gende aarin wọn.
Marun-un lawọn obinrin aarin wọn, Jumọkẹ Idris, Nikẹ Idris, Adeọla Adewale, Sharon Egiri ati Damilọla Ọmọniyi.
Awọn gende to ku ni: Abass Saliu, Gafar Ambali, Oriyọmi Adeyẹmi, Suleiman Saleh, Junior Ọjọọ, Abayọmi Ogunlẹyẹ, Alhassan Abdulahi, Kazeem Ọlagbajumọ, Rilwan Salau, Taiwo Wajud, Suleiman Adewale Njokwu Ogbonna, Njokwu Chinemenem, Okechukwu Chinanso, Wahab Azeez ati Adam Oluwọle.
Awọn to ku ni Ṣẹgun Solomọn, Wahab Korede, Micheal Ọladeji, Adeniyi Mustapha Gafar, Oluwatobi Senu, Afeez Sulaimọn, Surajudeen Jimọh, Ahmed Adamu, Nojeem Ajayi, Yusuf Lawal, Quadri Akanbi, Afeez Shodimu, Monday Joseph, Adigun Yahaya, Yusuf Saliu, Nuhu Umar, Abbey Sholọla, Benjamin Chalie, Amen Daniel, Samuel Igbogboye, Toni Nwokeji, Ibrahim Usman, Sulaiman Rasak, Haliru Abdulahim Usman Mohammed, Yusuf Ayinde, Lekan Salisu, Ibrahim Abukakar, Musa Yusuf, Micheal Francis, Rasheed Abashin, ati Saheed Dauda.
Gbogbo wọn ni wọn ti n ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn, Odumosu si ti ni tiṣẹ iwadii ba ti pari lawọn maa foju awọn afurasi naa han niwaju adajọ ki wọn le fimu kata ofin.