Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ni afurasi adigunjale kan, Ṣẹgun Idowu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wọn lo maa n figba gbogbo daamu awọn araalu Ògèlé, ati gbogbo agbegbe rẹ wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe wọn maa n ja awọn araalu lole nigba gbogbo.
ALAROYE gbọ pe lọjọ Keji, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni ọwọ palaba Ṣẹgun ṣẹgi lasiko to lọọ ja obinrin kan, Ọladele Nafisat, lole, nigba tiyẹn ko si nile lo gba ori ṣilin wọle, to si ji foonu ati ẹgbẹrun lọna aadọta Naira gbe ki ọwọ awọn araadugbo to tẹ ẹ, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
Nafisat, sọ fawọn ọlọpaa niluu Ògèlé, pe oun rin-irin-ajo lọ si ilu Ẹyẹnkọrin, lọjọ keji, oṣu Karun-un, ṣugbọn nigba ti oun wọle loun ri i pe ẹnikan ti gba ori ṣili wọle, to si n ji dukia oun, eyi lo mu k’oun fariwo ta, ti afurasi naa si sare jade, lo ba sa lọ, nigba to gbọ ariwo, ṣugbọn awọn araadugbo ri Ṣẹgun mu pẹlu foonu TECNO ati ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (50,000), to ji gbe lọwọ rẹ.
Agbefọba, Adefẹhinti Stephen, sọ pe wọn ni ọjọ ti pẹ ti Ṣẹgun atawọn yooku rẹ ti maa n ja araalu lole, eyi to ta ko iwe ofin ilẹ wa. Lọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni Agbefọba Adefẹhinti, gbe iwe ẹjọ afurasi yii lọ siwaju kootu Majisireeti kan niluu Ilọrin, nibi ti yoo ti lọọ ṣalaye ohun to sun un de ibi iṣẹ ole jija fun adajọ.