Owo ọlọpaa tẹ Abọlaji atọrẹ ẹ ti wọn faṣọ ṣọja jale l’Oṣogbo

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ Gabriel Abọlaji, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (35), pẹlu Samuel Mathew, ẹni ogun ọdun (20), ti wọn si ti wọ wọn lọ si ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Oṣogbo lori ẹsun idigunjale ati wiwọ aṣọ ṣọja lọna aitọ.

Agbegbe Old Garage, niluu Oṣogbo, lọwọ ti tẹ wọn pẹlu aṣọ ṣọja. Agbefọba to ko wọn wa si kootu, Ọgbẹni Elisha Oluṣẹgun ṣalaye pe ọwọ tẹ awọn mejeeji ọhun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, nibi ti wọn ti fẹẹ digunjale pẹlu aṣọ ṣọja.

Nigba ti wọn beere lọwọ awọn olujẹjọ boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi, wọn ni awọn jẹbi.

Adajọ Abayọmi Ajala faaye beeli silẹ fun ẹnikọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira pẹlu oniduuro kọọkan.

Wọn ti sun igbẹjo miiran si ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an ta a wa yii.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: