Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi awọn ọbayejẹ eeyan kan ṣe ge ẹran ara alaisan kan to ku sileewosan aladaani kan lọ n’Ibadan, ọwọ ọlọpaa ti tẹ diẹ ninu awọn oṣiṣẹ ileewosan naa.
O kere tan, mẹta ninu awọn oṣiṣẹ ọsibitu ọhun, Ibadan Central Hospital, to wa laduugbo Ọṣọṣami, n’Ibadan, ni wọn ti wa ninu atimọle awọn agbofinro bayii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, o ṣe diẹ ti iya agba naa ti n gba itọju nileewosan yii ko too dagbere faye loru ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, mọju ọjọ Aiku, Sannde,ọsẹ yii.
Njẹ ki awọn ọmọlooku lọọ gbe oku iya wọn kuro nileewosan yii lọ si mọṣuari, iyẹn ibi ti wọn maa n tọju awọn oku pamọ si ki wọn le raaye ṣeto ẹyẹ ikẹyin ati eto isinku iya naa, ni wọn ri i pe wọn ti ṣiṣẹ abẹ si iya wọn lara.
Ṣugbọn iṣẹ abẹ eleyii ki i ṣe iru eyi ti awọn akọṣẹmọṣẹ dokita maa n ṣe, awọn ọmọ eriwo ni wọn dọgbọn ge ẹran diẹ nibi agbari, apa ati ibi kọlọfin ara oku naa.
Nigba ti ọkan ninu awọn ọmọọlooku debẹ lati gbe oku iya wọn lọ ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lo ri i bi awọn ọmọ aye ti ṣe fọbẹ dara si iya ẹ lorikeerikee ara.
Lọgan ni baba naa sọ ọrọ yii di ariwo mọ awọn alaṣẹ ọsibitu ọhun lọwọ, ṣugbọn ko sẹni to jẹwọ pe oun mọ nnkan kan nipa iṣẹ abẹ aramọnda naa.
Awọn ẹbi oloogbe tun ya lọọ ba awọn alaṣẹ ileewosan naa laaarọ yii, wọn pariwo, pariwo le wọn lori, sibẹ, ko sẹni to jẹwọ, n lawọn ẹbi oloogbe ba fọrọ naa to awọn agbofinro leti.
Ni nnkan bii aago mẹta ọsan yii (Mọnde) lawọn ọlọpaa lọọ gbe gbogbo awọn oṣiṣẹ ọsibitu naa ti wọn ṣiṣẹ alẹ Sannde, mọju ọjọ Mọnde, fun iwadii to muna doko.
Inu atimọle awọn ọlọpaa to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, l’ALAROYE gbọ pe awọn eeyan naa wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.